Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti fidi rẹ mulẹ pe awọn ti n tọpasẹ ọmọ Hausa kan to sa lọ lẹyin to fi tipa ba ọmọbinrin ẹni ọdun mejila kan lo pọ niluu Igbọkọda, ti i ṣe ibujokoo ijọba ibilẹ Ilajẹ.
ALAROYE gbọ pe lasiko tọmọbinrin ta a forukọ bo laṣiiri yii n ba iya rẹ, Joy, kiri pọfupọọfu lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, ni Aboki naa ki i mọ ile akọku kan, to si fipa ba a lo pọ karakara.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun, Abilekọ Joy to jẹ iya ọmọbinrin ọhun ni ọmọ oun funra rẹ lo sọ foun pe oun fẹẹ kiri ọja lọ lẹyin to pada de lati ile-iwe lọjọ naa, kawọn le rowo san awọn owo to yẹ ko san nileewe.
O ni jinnijinni ti kọkọ mu oun nigba ti oun reti rẹ ko pada wale, ṣugbọn ti oun ko tete ri i. Nnkan bii aago meje alẹ ni iyaale ile yii ni oun kan deedee ri ọmọ oun to pada wa sile, to si ti rẹ ẹ kọja sisọ.
O ni bo ṣe fẹẹ maa ṣalaye ohun toju rẹ ri loun ṣakiyesi pe o bẹrẹ si i lọ silẹ diẹdiẹ, titi to fi ṣubu lulẹ, to si daku lọ gbari. Obinrin yii ni niṣe lawọn sare gbe e lọ si ọsibitu, nibi to ti pada laju saye lẹyin ti wọn ṣiṣẹ abẹ fun un.
Lẹyin to ji saye tan lo ṣẹṣẹ waa royin itu ti ọkunrin Aboki ọhun fi oun pa, o ni gbogbo abẹ ọmọbinrin naa lo ti faya latari bi ọkunrin mMọla yii ṣe ṣe e yankanyankan.
Joy ni kiakia loun ti fi iṣẹlẹ yii to awọn agbofinro ilu Igbọkọda leti, ti awọn si jọ ko rẹirẹi lọ sinu ile akọku naa, nibi ti awọn ti ṣalabaapade ọkan-o-jọkan awọn ẹri to fidi iwa buruku ti ọkunrin naa hu mulẹ.
Wọn wa aboki ọhun de ibi to n gbe, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ fawọn nigba tawọn to mọ ọn daadaa sọ pe o ti sa pada si ipinlẹ Kebbi to ti wa.
Obinrin naa ni loootọ lawọn ọlọpaa n leri leka pe ọwọ awọn ko ni i pẹẹ tẹ afurasi naa nibi yoowu ko le sa pamọ si, amọ ti ko ti i si aridaju kankan lori ibi ti ọkunrin Hausa ọhun wa ni gbogbo asiko yii.
Iyaale ile yii ni owo gọbọi loun na fun itọju ọmọ oun lọsibitu to ti gba itọju, o ni ohun to le mu inu oun dun ni ki ọwọ tẹ ẹ, ko si waa jiya to tọ labẹ ofin.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori rẹ, awọn si ti n ṣètò bi ọwọ yoo ṣe tẹ ẹ, ko le waa foju wina ofin.