Ọlọpaa o le sọ pe ka ma ṣewọde ayajọ EndSARS, a maa ṣe e -Oduala

Faith Adebọla, Eko

 Ọkan ninu awọn to ṣagbatẹru iwọde ta ko awọn ọlọpaa SARS tijọba ti fofin de, Bọlatito Oduala, ti inagijẹ rẹ n jẹ Savvy Rinu ti sọ pe ko sohun to le da awọn ọdọ lọwọ kọ lati ma ṣewọde logunjọ, oṣu kẹwaa yii, ni iranti iṣẹlẹ EndSARS to waye lọdun to kọja.

Oduala sọrọ yii lori ikanni ayelujara rẹ lati fesi si ikilọ tileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ṣe ninu atẹjade ti wọn fi lede lọjọ Aje, Mọnde yii, pe awọn o ni i faaye gba iwọde kankan ni iranti iṣẹlẹ EndSARS.

Atẹjade ọhun, eyi ti Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Hakeem Odumosu, buwọ lu sọ pe ipo ẹlẹgẹ ni eto aabo ipinlẹ Eko wa, bẹẹ lo si ri kaakiri orileede yii, tori naa awọn ko ni i faaye gba ẹnikẹni tabi awọn ọdọ lati gun le iwọde eyikeyii lọjọ ayajọ EndSARS, o ni irufẹ iwọde bẹẹ le di eyi tawọn janduku atawọn ajinigbe le darapọ mọ lati dana ijangbọn tabi ki wọn wu awọn araalu lewu.

Odumosu ni gbogbo ilana ati igbesẹ to bofinmu, to wa nikaawọ awọn agbofinro lawọn yoo gbe lati gbegi dina iwọde tabi ifẹhonuhan lọjọ naa, bẹẹ lo si kilọ fawọn obi lati ba awọn ọmọ wọn sọrọ nibi ti wọn ti maa n gbọran.

Ṣugbọn Oduala sọ ninu ọrọ to kọ soju opo ayelujara rẹ ọhun pe ko si nnkan ija tawọn ọlọpaa le lo ti yoo di awọn lọwọ lati ṣewọde lọjọ naa, tori ẹtọ awọn ọdọ ni, awọn si ti ṣeto bo ṣe yẹ.

O lawọn o ni lati gba iyọnda lọwọ ileeṣe ọlọpaa ki iwọde too waye, bẹẹ ni ki i ṣe ojuṣe kọmiṣanna lati kọkọ fọwọ si i tabi tako o.

Savvy Rinu kọ ọ sibẹ pe: “CP Hakeem Odumosu, o o laṣẹ lori ọrọ yii, bẹẹ lo o lẹtọọ kankan lati kilọ, tabi gbegi dina fun awọn to fẹẹ ṣe iwọde alaafia. Oṣiṣẹ ijọba ni o, ojuṣe rẹ si ni lati pese aabo, ko o si daabo bo ẹtọ awọn to maa ṣe iwọde.”

Oduala ni awọn o ni i wọgi le iwọde naa, dandan ni ko waye bawọn ṣe ṣeto rẹ.

Leave a Reply