Ọlọpaa obinrin lawọn Fulani onimaaluu yii ji gbe o

“Mọto n gbe Insipẹẹtọ ọlọpaa obinrin kan lati Ayetoro, Yewa, lọ si Abẹokuta ni ipinlẹ Ogun. Lojiji ni wọn kan awọn Fulani onimaaluu ti wọn ti gbegi dana, ni wọn ba da wọn duro. Nibi ti wọn ti n wọ obinrin yii bọ silẹ, dẹrẹba to wa lẹyin wọn toun naa n gbe obinrin mi-in bọ ri wọn , niyẹn ba fẹe sare yi mọto pada ko họ, ṣugbọn niṣe lawọn Fulani yii yinbọn pa a. Ni wọn ba ji obinrin insipẹẹtọ yii, ati obinrin to wa ninu moto keji gbe wọ inu igbo lọ.”

Bayii ni olori awọn ọlọpaa Zone 2, ni Onikan-an, Eko, AIG Ahmed Ilyasu ti wi nigba to n fi awọn Fulani to wa ninu fọto yii han awọn oniroyin lanaa ode yii, lẹyin ti ọwọ ti to wọn. Ọga ọlọpaa naa ni ọjọ mẹta ni awọn obinrin mejeeji yii ṣe lọdo awọn Fulani ajinigbe naa, ki wọn too fi wọn silẹ lẹyin ti wọn ti gba owo nla lọwọ awọn mọlẹbi wọn.

Orukọ awọn Fulani yii ni Adamu Saliu, Ibrahim Muhammed, Abubakar Sadiq, Tambaye Muhammed, Adamu Sulaiman ati Musa. Ilyasu sọ pe awọn Fulani yii naa ni wọn ji ọkunrin sifuu-difẹnsi kan gbe, iyẹn Alaaji Umar ati Alaaji Oro ẹlẹran. Miliọnu mẹta ni wọn gba lọwọ Umaar ki wọn too fi i silẹ, ṣugbọn lẹyin ti wọn gba miliọnu mẹrin lọwọ awọn ẹbi Alaaji Oro ẹlẹran, niṣe ni wọn tun pa a.

Gbogbo awọn ọdaran naa ni wọn fẹnu ara wọn jẹwọ iṣẹ buruku ti wọn ṣe yii niwaju awọn oniroyin, Ọga Ọlọpaa Ilyasu si sọ pe wọn yoo fi oju a ile-ẹjọ laipẹ rara.

 

One thought on “Ọlọpaa obinrin lawọn Fulani onimaaluu yii ji gbe o

Leave a Reply