Ọlọpaa Ogun ni ko saaye fawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to fẹẹ ṣoro lọjọ keje, oṣu keje

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ọjọ keje, oṣu keje, ọdọọdun ki i ṣe ọjọ lasan lọdọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun, wọn maa n fi i ṣoro ẹgbẹ wọn pẹlu jagidijagan ni. Tọdun yii naa ko ni i yatọ bawọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣe wi, ṣugbọn wọn ni yoo daa kawọn ọmọkọmọ to ba lero iru ẹ lọkan tete gbagbe ẹ, nitori ẹni tọwọ ba tẹ ko ni i le royin tan.

Ọjọ Aje, ọsẹ yii, ti i ṣe Mọnde, ọjọ karun-un, oṣu keje, ni Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, fi ikilọ sita fawọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun.

O ni olobo ti ta awọn pe awọn ẹgbẹ okunkun nipinlẹ Ogun fẹẹ ṣayọjọ 7/7, iyẹn ọjọ keje, oṣu keje.

Alukoro ni fun idi eyi, awọn ọlọpaa SWAT, awọn to n ri si ẹgbẹ okunkun, awọn to n ri si ijinigbe pẹlu awọn DPO atawọn eria kọmanda ni wọn ti fun laṣẹ lati mu ẹgbẹkẹgbẹ tabi ọmọkọmọ to ba loun n sami ọjọ keje yii lọna ti wọn maa n gba ṣe e, to jẹ wọn o ni i jẹ kawọn eeyan to n lọ sibi iṣẹ oojọ wọn rọna lọ.

Wọn ni ẹni tọwọ ba tẹ to loun n ṣọdun 7/7, kele yoo gbe e nibi to ti n ṣe e ni.

Iyẹn nikan kọ, bakan naa nileeṣẹ ọlọpaa kilọ fawọn olotẹẹli, wọn ni ki wọn ri i pe wọn ko gba awọn to ba fẹẹ kora jọ lati ṣeranu kan lotẹẹli wọn, nitori otẹẹli ti wọn ba ti kẹẹfin iru ẹ, wọn yoo mu ẹni to ni in mọ awọn ọmọkọmọ naa ni.

Wọn kilọ fawọn obi naa pe ki kaluku fa ọmọ ẹ leti, ọmọ tọwọ ba tẹ lagbo iwakiwa ni 7/7, obi rẹ ko ni i le gba a silẹ o.

Nipa aabo araalu, Alukoro sọ pe kẹnikẹni ma ṣe bẹru, ki wọn jade lọ sibi iṣẹ wọn lọjọ naa, kinni kan ki yoo ṣe wọn, nitori ọjọ keje ko yatọ sọjọ yooku, awọn oniṣẹ ibi lo n pọn irọn lewe kiri.

Leave a Reply

%d bloggers like this: