Ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori iku tọkọ-taya ti wọn ba oku wọn ninu ile l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn ọlọpaa ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ awọn oku mẹta ti wọn ba ninu ile kan laduugbo Aratusin, Danjuma, niluu Akurẹ, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmi Ọdunlami, lo sọrọ yii nigba ta a kan si i lori aago lati fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ.

Ọdunlami ni bo tilẹ jẹ pe iwadii awọn ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ kayeefi naa, sibẹ, ohun tawọn agbofinro ṣakiyesi nigba ti wọn kọkọ ri awọn oku ọhun fihan pe awọn amookunsika kan ni wọ pa wọn fun idi kan tabi omiiran.

Ọdọmọkunrin kan tawọn eeyan mọ si Akinrọ Blessing Ojo, ololufẹ rẹ, Mary Igwe, pẹlu ọrẹ wọn kan ti wọn porukọ rẹ ni Lamidi Sherifat, ni wọn ba oku wọn ninu ile iyagbẹ ibi ti wọn n gbe ni Aratusin.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, awọn ẹbi oloogbe ọhun pẹlu iranlọwọ awọn agbofinro ni wọn lọọ ja ilẹkun ile wọn lọjọ naa lẹyin ọjọ diẹ ti wọn ko ri wọn pe lori aago tabi ki wọn jade si gbangba.

Lẹyin ti wọn raaye wọle tan ni wọn ri oku awọn mẹtẹẹta ninu tọlẹẹti ibi ti wọn wọ wọn ju si, ti wọn si tilẹkun mọ wọn.

Awọn foonu ati kọmputa agbeletan to jẹ tawọn oloogbe ọhun la gbọ pe wọn ba lori tabili ti ko sẹni to fọwọ kan wọn.

Oku awọn mẹtẹẹta la gbọ pe wọn ti ko lọ si mọṣuari ileewosan ijọba to wa l’Akurẹ, nigba ti iwadii awọn ọlọpaa ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ ọhun.

Leave a Reply