Adewumi Adegoke
O ṣee ṣe ki ileeṣẹ ọlọpaa lọọ ṣe ayẹwo si oku ọmọ gbajumọ olorin taka-sufee nni, Ifeanyi Adeleke, to ku lojiji lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, sinu odo iwẹ baba rẹ to wa nile wọn ni Banana Island, l’Erekuṣu Eko.
Alaroye gbọ pe igbesẹ yii wa lara iwadii ti awọn ọlọpaa maa n ṣe lati le mọ iru iku to pa ẹni kan ti iru iṣẹlẹ bayii ba waye. Ṣugbọn ti awọn mọlẹbi oku ba ni awọn ko fẹ, awọn agbofinro ko ni i ṣe e.
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti da meji ninu awọn oṣiṣẹ ile Davido ti wọn ko ni ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, duro sọdọ won fun iwadii si i.
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, lo sọ eleyii di mimọ. O ni lẹyin ọpọlọpọ iwadii ati ifọrọwerọ pẹlu awọn eeyan naa, awọn ti da mẹfa ninu awọn oṣiṣẹ naa silẹ pe ki wọn maa lọ. Bẹẹ ni nani to n tọju ọmọ naa ati alase ile wọn wa pẹlu awọn fun ifọrọwerọ siwaju si i.
Bakan naa ni iwadii ti n lọ lati ṣe ayẹwo fọnran aṣofofo ti wọn maa n gbe sinu ile lati mọ ohun to n lọ.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni ọmọ naa ku sinu odo iwẹ atọwọda to wa nile wọn ti wọn n pe ni Swimming pool. Baba ati iya ọmọ yii ko si nile nigba ti iṣẹlẹ na waye.