Ọlọpaa ti mu awọn Fulani to pa Alaaja Sherifat, ọga ileepo l’Ayetẹ

Ọlawale Ajao, Ibadan

O kere tan, ọwọ awọn agbofinro ti tẹ marundinlogoji (35) ninu awọn afurasi ọdaran to n da awọn ara ipinlẹ Ọyọ láàmú.

Mọkanla ninu wọn lawọn oluwadii fura sí pe  o yinbọn pa Alhaja Sherifat, iya to ni ileepo kan ti wọn n pe ni Subawah Filling Station, niluu Idere, nipinlẹ Ọyọ.

Ṣaaju lawọn ọdaju eeyan yii ti kọkọ yinbọn pa awọn ọmọde méjì kan, Babatunde Ọmọwumi ati Toriọla Kudiratu, nibi ti wọn duro sí nitosi ileepo yii.

Lẹyin naa ni wọn wọ Alhaja Sherifat, ẹni to nileepo naa lọ sinu igbo, nitosi ileepo ẹ ọhun, nibi ti wọn pada yinbọn pa a si.

Nigba to n ṣafihan awọn afurasi ọdaran naa fawọn oniroyin n’Ibadan, ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Ngozi Ọnadeko, sọ pe AK 47, iru ibọn tawọn ọlọpaa maa n lo pelu ibọn ilewọ kan, ati ada tawọn ọdaju eeyan naa fi n dá awọn  eeyan loro lawọn agbofinro ka mọ wọn lọwọ, ti wọn sì ti gba lọwọ wọn.

CP Onadeko ṣalaye pe “Ohun tá a kọkọ ṣe nigba ti wọn fi iṣẹlẹ yẹn to wa leti ni pe awọn eeyan mi (ọlọpaa) kọkọ gbe awọn oku mẹtẹẹta lọ sí moṣuari ka tóo bẹrẹ iwadii ijinlẹ lori ẹ lẹsẹkẹsẹ.

“Ninu iwadii wa la ti ri awọn afurasi mẹsan-an mu lori iṣẹlẹ yẹn. A sì rí í pé ọkàn ninu wọn fi síìmù mi-in sinu foonu Alhaja yẹn lati pè awọn eeyan kan.

Ẹgbẹrun mejidinlaaadoje (N138,000) naira la ka mọ awọn afurasi ọdaran yẹn lọwọ.

Ni kete ti awọn agbofinro ba ti pari iwadii wọn ni wọn yoo gbe awọn afurasi ọdaran naa lọ si kootu gẹgẹ bi ọga agba awọn ọlọpaa ṣe fìdí ẹ mulẹ.

 

 

Leave a Reply