Ọlọpaa ti mu Baba Ijẹṣa onitiata, wọn lo fipa ba ọmọ ọdun mẹrinla lo pọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Gbajugbaja oṣere tiata to maa n dẹrin-in poṣonu nni, Ọlanrewaju Omiyinka, tawọn eeyan mọ si Baba Ijẹṣa, ti wa lakolo ọlọpaa ipinlẹ Eko bayii, ohun ti wọn mu un fun ni pe wọn lo fipa ba ọmọbinrin tọjọ ori ẹ ko ju mẹrinla lọ, lo pọ

Teṣan ọlọpaa Sabo, labala ibi ti wọn ti n gbọ ẹsun ifipanilopọ ni ọrọ Baba Ijẹṣa wa bayii, l’Ekoo.

Obinrin kan, Adekọla Adekanya, lo mu ẹjọ oṣere yii lọ si teṣan naa lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹrin yii, pe ọkunrin ọmọ bibi ilu Ile-Ifẹ naa ti n huwa abuku pẹlu ọmọdebinrin ti wọn forukọ bo laṣiiri yii tipẹ.

Iwadii awọn ọlọpaa fidi ẹ mulẹ pe latigba tọmọbinrin naa ti wa lọmọ ọdun meje pere ni Baba Ijẹṣa, ẹni ọdun mejidinlaaadọta (48) ti n ba a lo pọ.

Gẹgẹ bawọn ọlọpaa si ti wi, wọn ni Baba Ijẹṣa ti jẹwọ pe loootọ loun n ba ọmọ kekere naa lo pọ. Koda, wọn ni kamẹra ka a silẹ lai jẹ pe ọkunrin naa mọ, iyẹn nigba to wa ninu ile obinrin to lọọ fẹjọ ẹ sun ni teṣan yii.

Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, ti paṣẹ pe ki iwadii to lagbara bẹrẹ lori ọrọ oṣere tiata Yoruba ọhun, bẹẹ lo ṣeleri pe oun yoo ṣiṣẹ lori ẹ bi ofin ṣe sọ

  Ṣugbọn iṣẹlẹ yii ko ṣee dakẹ si fawọn eeyan kaakiri ibi ti wọn ti mọ Lanrewaju Omiyinka, ọpọ eeyan to fẹran rẹ nitori bo ṣe maa n da wọn laraya ko si fẹẹ gba iṣẹlẹ naa gbọ, kaluku n sọ pe ṣe Baba Ijẹṣa le ṣe bẹẹ ṣa, nigba ti ki i ṣe pe ko niyawo nile.

Iwadii awọn ọlọpaa ni yoo tubọ ṣalaye bo ṣe ṣẹlẹ gan-an gẹgẹ bawọn agbofinro ti wi, ṣugbọn titi ti wọn yoo fi pari iwadii naa, ohun to ṣi n lọ kari aye ni pe, Baba Ijẹṣa onitiata fipa ba ọmọ ọdun mẹrinla lo pọ!

 

Leave a Reply