Ọlọpaa ti mu Jide, wọn ni ko waa ṣalaye bi Habeeb ti wọn jọ sun ṣe dawati ni Bariga

Faith Adebọla, Eko

Ẹjọ to wa lọrun ọmọkunrin kan, Jide, ki i ṣe kekere rara, ẹjọ nla ni, teṣan ọlọpaa lo si wa ba a ṣe n sọ yii, wọn ni ko ṣalaye bi eeyan meji ti wọn wọle lọọ sun ṣe ku ẹni kan nigba tilẹ mọ, latari bi ọrẹ ẹ, Habeeb Abdulsalam, ṣe dawati loru mọju.

Agbegbe Bariga, ninu ile kan to wa l’Opopona Odulesi, niṣẹlẹ yii ti waye, ọrẹ ni Jide ati Habeeb to n ṣiṣẹ kọlekọle, to si tun n kawe lọwọ ni Poli Eko (LASPOTECH), ba a ṣe gbọ. Awọn mejeeji ti n ba ọrẹ wọn bọ tipẹ, wọn si jọ n gbe inu yara kan naa nile ti wọn haaya ọhun ni.

Wọn ni alẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹjọ, lawọn mejeeji jọọ wọle lọọ sun ninu yara wọn bi wọn ti maa n ṣe, ṣugbọn nigba tilẹ mọ, Jide nikan ni wọn ri to jade sita, Habeeb ti dawati kilẹ too mọ, wọn o ri oku ẹ, wọn o ri aaye ẹ pẹlu.

Ṣe wọn ni ‘ọmọ ẹni ku san ju ọmọ ẹni sọnu lọ’, latigba naa ni wọn ti ko si wiwa Habeeb lawari, ṣugbọn ko ti i sẹni to gbọ ‘mo ko o’ birikila ọhun titi di ba a ṣe n sọ yii.

Ẹgbọn Habeeb, Shitu Abdusalam, sọ fun Ajọ Akoroyinjo ilẹ wa (NAN) pe inu iporuuru ọkan ati idaamu ni gbogbo mọlẹbi wa latigba tiṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ, awọn si ti lọọ fọrọ ọhun to awọn agbofinro leti ni teṣan ọlọpaa Ilajẹ, ni Bariga.

Awọn ọlọpaa ranṣẹ si Jide, ṣugbọn ko tete yọju, igba tọwọ to o lọjọ Ẹti to kọja yii lawọn ọlọpaa sọ ọ sahaamọ.

Shittu ni lakọọkọ tọmọkunrin naa sọnu, nọmba foonu rẹ n lọ, ṣugbọn ko sẹni to gbe e, titi ti nọmba naa ko fi lọ mọ, ko si sẹni to le sọ boya foonu naa ti ku ni, tabi ohun aburu kan ti ṣẹlẹ sẹni to ni in. O lawọn o ti i gba ipe boya awọn ajinigbe ni wọn ji i gbe, ẹnikẹni o si ti i beere owo itusilẹ lọwọ awọn.

Leave a Reply