Ọlọpaa ti mu Suleiman, ogbologboo ọmọ ẹgbẹ okunkun to n pa wọn n’Ijẹbu

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

O pẹ ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti n wa ọkunrin yii, Suleiman Ganiyu, ọmọ ẹgbẹ okukun Ẹiyẹ ti wọn ni ipakupa lo n paayan l’Agọ-Iwoye. Ọjọ kẹrinla, oṣu kẹta yii, ni wọn ri i mu ni Oru-Ijẹbu.

Eyi ti wọn fi ri i mu yii paapaa ṣe awọn eeyan ni kayeefi, nitori aburo rẹ to jẹ akẹkọọ nileewe Itamẹrin Comprehensive High School, Ago-Iwoye, ni wọn lu, ni Suleiman ba fibinu gba ileewe naa lọ pẹlu ibọn lọwọ, lo ba bẹrẹ si i yinbọn lai ro ti ohun to le ṣẹlẹ bi ibọn ọhun ba ba ẹnikẹni.

Ohun to n ṣe lọwọ ree lọjọ kẹrinla, oṣu kẹta yii, ti olobo fi ta agọ ọlọpaa Agọ-Iwoye, ti DPO, CSP Paul Omiwọle, fi ko awọn ikọ rẹ lẹyin lati lọọ mu Suleiman, ṣugbọn nigba ti wọn yoo fi debẹ, o ti sa lọ.

Ibi to n fara pamọ si l’Opopona Imosan, l’Oru-Ijẹbu ni wọn ka a mọ, ti wọn si mu un ṣinkun.

Nigba to n ṣalaye itu to ti pa fawọn ọlọpaa, Suleiman jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ loun.

O ni ọdun 2014 loun wọ ẹgbẹ naa nileewe Ọlabisi Ọnabanjọ Yunifasiti. Ati pe ọpọlọpọ awọn to mu oun wọnu ẹgbẹ naa ti ku bayii.

O fi kun un pe oun loun pa ẹnikan ti wọn n pe ni Awokale Oluṣẹgun, ti inagijẹ ẹ n jẹ Lala. O ni ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu keji, ọdun 2020, loun pa a nigba tawọn n ja ija agba. Ganiu sọ pe awọn ọlọpaa kede pe wọn n wa oun nigba yẹn.

Bakan naa lo jẹwọ pe oun loun pa ẹnikan to n jẹ Babasco ati ẹlomi-in to n jẹ Dapọ, n’Ijẹbu-Igbo, lọdun 2015. Ija agba naa ni Ganiu sọ pe o ṣẹlẹ laarin oun atawọn eeyan meji naa ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun Aye, to fi di pe oun ran wọn sọrun.

Iwadii awọn ọlọpaa siwaju si i fidi ẹ mulẹ pe ọmọkunrin yii lo wa nidii awọn ikọlu ẹgbẹ okunkun to n waye ni Ijẹbu-Oru, Ijẹbu-Igbo, Agọ-Iwoye, Ilaponu ati Awa Ijẹbu.

Ọmọ Ijẹbu-Oru ni Suleiman gẹgẹ bo ṣe wi. O ni awọn kan ni wọn lu aburo oun nileewe Itamẹrin Comprehensive High School, oun fẹẹ ṣakara wọn lo jẹ koun mu ibọn lọ sibẹ.

Alukoro ọlọpaa Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, sọ pe awọn ti taari ẹ sẹka iwadii ẹsun bii eyi, gẹgẹ bi ọga awọn, CP Edward Ajogun, ṣe paṣẹ.

Leave a Reply