Ọlọpaa to ba ṣe aṣemaṣe, ẹ ya fidio ẹ

Aderounmu Kazeem

“Ti a ba ri ẹnikẹni to ni iwa ọdanran kan lọwọ ti inu ẹ n dun wi pe ileeṣẹ ọlọpaa ti ko awọn SARS nilẹ patapata, iru awọn eeyan bẹẹ n tan ara wọn jẹ ni o, nitori awọn ẹṣọ agbofinro naa yoo ṣi wa daadaa, atunṣe ati atunto nijọba fẹẹ ko waye lori iṣẹ wọn.”

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, DCP Frank Mba lo ṣe bayii sọrọ, lasiko ti gbajumọ olorin nni, Azeez Fashọla, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Naira Marley, ṣe ifọrọ-wani-lẹnu-wo fun un lori ẹrọ ayelujara ẹ, Instagiraaamu.

̀Ọkunrin ọlọpaa yii fi kun ọrọ ẹ wi pe ko rọrun ki ijọba ko awọn ẹṣọ to n gbogun ti iwa ọdaran kuro nilẹ bẹẹ, paapaa bi oriṣiiriiṣi iwa ọdaran ṣe pọ nigboro lasiko yii.

O ni kaka ki ileeṣẹ ọlọpaa fagile ẹka ẹṣọ ẹ yii, atunṣe ati atunto gidi lo maa waye, ti awọn ẹṣọ naa yoo si yipada si rere.

Mba sọ pe gbogbo iwa to le tabuku ba iṣẹ naa lawọn yoo mojuto bayii, ati pe ẹṣọ ti ọwọ ba tẹ pẹlu awọn iwa ti ileeṣẹ ọlọpaa ni wọn ko gbọdọ ṣe mọ yoo rugi oyin.

Bẹẹ gẹgẹ ni agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa yii sọ pe ọlọpaa kankan ko lẹtọọ lati maa fiya jẹ ọkunrin to ba dirun tabi ṣe adamọdi irun Dada sori. Bakan naa lo fi kun un pe eeyan le fi foonu ẹ ya fidio ọlọpaa ti iṣẹ ẹ ba ti n tayọ ohun ti ofin ni ko ṣe, ṣugbọn eni to ba fẹẹ ya iru fidio bẹẹ gb̀ọdọ ṣe pẹlẹ, paapaa tiru ọlọpaa bẹẹ ba gbe ohun ija oloro dani

Tẹ o ba gbagbe, ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe ko gbọdọ si ẹṣọ agbofinro to tun gbọdọ gbegi dina lojupopo mọ, bẹẹ ni wọn ko gbọdọ maa tọwọ bọ awọn eeyan lapo kiri.

Leave a Reply