‘Ọlọpaa to ba tu apo eeyan wo, tabi fipa gba ẹrọ kọmputa yoo wọ gau’

Aderounmu Kazeem

Ọga ọlọpaa ni Naijiria, Muhammed Adamu ti paṣẹ wi pe ọlọpaa kankan ko gbọdọ tun gbegi dina loju popo mọ, bẹẹ ni wọn ko gbọdọ maa yẹ apo awọn eeyan wo, ẹni to ba si ṣe bẹẹ, yoo fẹnu fẹra daadaa.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, Ọgbẹni Frank Mba, fọwọ si ni ọga agba patapata fun awọn ọlọpaa lorilẹ-ede yii ti sọrọ ọhun fawọn oniroyin.

Ninu ẹ naa lo ti sọ pe, awọn mi-in tọrọ ọhun tun kan ni ileeṣẹ ọlọpaa to n gbogun ti awọn iwa janduku bii ẹgbẹ okunkun, ijinigbe atawọn iwa ọdaran mi-in to lodi sofin.

Wọn lawọn ẹsọ agbofinro yii ko tun gbọdọ maa da mọto duro loju popo maa gbọn inu ẹ yẹbẹyẹbẹ mọ, bẹẹ lawọn to n le awọn ̀ọmọ yahoo kiri, ti wọn a maa tu apo ati ẹrọ kọmputa wọn naa gbọdọ sinmi.

Bakan naa lo sọ pe o ti di iwa ọdaran fun ọlọpaa ti ko ba wọṣọ lati maa gbebọn kiri, tabi da mọto duro kiri ojupopo. Bẹẹ lo fi kun un pe, wahala ni yoo da fun ọlọpaa tọwọ ba tẹ pe o huwa idojutini ninu iṣẹ agbofinro.

Ohun ti ALAROYE gbọ pe o mu ileeṣẹ ọlọpaa gbe igbesẹ yii ni bi awọn kan ṣe n lo iṣẹ agbofinro fi huwa ti ko ba ofin mu, eyi to n ko abuku ba iṣẹ ọlọpaa.

Ọga ọlọpaa ti sọ pe, agbofinro kankan ko gbọdọ maa rin kiri, tabi gbe igi dina loju popo, ti wọn yoo si maa tu foonu awọn eeyan wo, tabi tu ẹrọ kọmputa ẹnikẹni wo. O ni, iṣẹ ti ijọba ran awọn ẹsọ agbofinro ni ki wọn gbogun ti idigunjale, ijinigbe atawọn iwa ọdaran mi-in, ati pe ko sẹni to ran wọn ki wọn maa yẹ apo wo, tabi hu iwa ilọnilọwọgba fun araalu.

 

Leave a Reply