Ọlọpaa to n halẹ m’awọn ti mọto wọn ni gilaasi tintẹẹdi l’Ekoo ti n kawọ pọnyin rojọ

Faith Adebọla, Eko

 Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti mu Inspẹkitọ Dele Reuben, ọlọpaa to fooro ẹmi awakọ kan loju popo laipẹ yii, sahaamọ, wọn si ti bẹrẹ igbẹjọ abẹle lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, HSP Benjamin Hundeyin, lo sọrọ yii di mimọ ninu atẹjade kan to fi ṣowọ s’ALAROYE lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, lori iṣẹlẹ yii.

Hundeyin ni fidio to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara laarin ọsẹ yii, eyi to ṣafihan bi ọlọpaa naa ṣe fiya jẹ ọlọkọ adani kan latari pe gilaasi ọkọ rẹ dudu, ko si niwee aṣẹ lati lo gilaasi ọkọ ti ko mọlẹ bẹẹ, o ni wọn ta atare fidio naa de ọdọ Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, CP Abiọdun Alabi si paṣẹ pe ki wọn wo fidio naa lawofin, ki wọn ṣawari ọlọpaa to wa ninu rẹ, ki wọn si fọwọ ṣinkun ofin gbe e.

Eyi lo mu Agbofinro Dele Reuben de olu-ileeṣẹ ọlọpaa Eko, n’Ikẹja, o si ti n kawọ pọnyin rojọ, gẹgẹ bii ilana awọn ọlọpaa, nipa idi to fi huwa aitọ naa.

Alukoro ọlọpaa sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti so ofin nipa lilo gilaasi ọkọ dudu rọ, tori wọn n ṣe atunṣe sawọn ikanni ati akọsilẹ wọn, wọn si ti kede pe ki ọlọpaa kankan ma ṣe yọ onimọto eyikeyii lẹnu lori iwe aṣẹ lati lo gilaasi dudu, titi digba tofin naa yoo tun bẹrẹ iṣẹ pada.

O ni sẹria to ba yẹ lawọn maa fun Inspẹkitọ Dele yii, ti iwadi ba fihan pe loootọ lo jẹbi.

O dupẹ lọwọ awọn to ya fidio naa, ti wọn si tatare rẹ sawọn ọlọpaa, o si tun ṣekilọ fawọn agbofinro lati ṣọra fun iwa ibajẹ ati fifiya jẹ araalu lọna aitọ, tori iru aṣa bẹẹ le ṣakoba fun wọn ati ileeṣẹ ọlọpaa.

Leave a Reply