Ọlọpaa to pa Ọlaoye sotẹẹli l’Ado-Ekiti ti dero kootu

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Igbẹjọ ọlọpaa to yinbọn pa ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelọgbọn kan, Abayọmi Ọlaoye, loṣu to kọja ti bẹrẹ nilẹ-ẹjọ Majisreeti agba to wa niluu Ado-Ekiti.

Tizhe Goji, ẹni ọdun mejidinlogoji, ni wọn fẹsun kan pe o huwa naa lọjọ kọkanlelogun, oṣu to kọja, nile itura Queen’s Court, to wa loju ọna to lọ si Ikẹrẹ-Ekiti lati Ado-Ekiti.

Awọn to mọ nipa iṣẹlẹ naa fẹsun kan Tizhe pe oun atawọn ti wọn tẹle ọga ọlọpaa kan wa si otẹẹli ọhun ni wọn jọ n dawọọ idunnu ti afurasi naa fi yinbọn pa oloogbe to jẹ akọṣẹmọṣẹ nipa ẹrọ ayaworan CCTV yii.

ALAROYE gbọ pe bọọlu ni Ọlaoye atawọn mi-in n wo nileetura naa lalẹ ọjọ iṣẹlẹ ọhun ti ọlọpaa yii fi yinbọn lu oun ati ọkunrin kan to n jẹ Idris, ẹni tibọn ba lẹsẹ, to si n gba itọju lọwọ nileewosan di akoko yii.

A gbọ pe nigba ti Tizhe atawọn ọlọpaa ẹgbẹ ẹ ri i pe awọn ti daran ni wọn sare gbe awọn tibọn ba lọ si leewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ekiti to wa ni Adebayọ, l’Ado-Ekiti, bẹẹ ni wọn fi mọto wọn silẹ sinu ọgba ọsibitu naa, wọn si sa lọ.

Kaadi idanimọ Tizhe lo kọkọ ko ba a, nitori awọn eeyan ri i ninu mọto ti wọn gbe silẹ ọhun, ọjọ keji lọwọ awọn agbofinro si tẹ ẹ.

Nigba ti Inspẹkitọ Caleb Leramo ka ẹsun ipaniyan si Tizhe lẹsẹ nile-ẹjọ lọsẹ to kọja, o ni o jẹbi labẹ ofin iwa ọdaran tijọba Ekiti ṣagbekalẹ lọdun 2012, oun si ti fi ẹda iwe ẹ sọwọ si ẹka to n gba ile-ẹjọ nimọran  (DPP) fun igbesẹ to kan.

Nitori bi ẹjọ naa ṣe ri, ko sẹni to beere ọrọ lọwọ olujẹjọ, ṣugbọn Amofin Ọla Abiọla to duro fun un rọ kootu naa lati sun igbẹjọ sọjọ ti ko pẹ rara.

Nigba ti Majisreeti-agba Abdulhamid Lawal gbe ẹbẹ naa yẹwo, o sun igbẹjọ sọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii, bẹẹ lo ni kootu naa yoo duro de imọran DPP.

Leave a Reply