Ọlọpaa wa ibuba awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan n’Ikorodu, ọwọ tẹ meje ninu wọn

Faith Adebọla, Eko

Awari ti wọn lobinrin n wa nnkan ọbẹ lawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ fi wiwa awọn ọdọ to n ṣẹgbẹ okunkun n’Ikorodu ṣe lọjọ Aiku, Sannde ọsẹ yii, awọn afurasi meje lọwọ ba, wọn lọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ ni wọn.

Orukọ awọn to ko sakolo naa ni: Abọlaji Abayọ,  ẹni ọdun mọkanlelogun, Josiah Ofem, ẹni ọdun mẹtadinlogoji. Oluwapẹlumi Oyeyinka, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn loun, Lamidi  Taofeeq, ẹni ọdun mọkanlelogoji, ati Rabiu Ganiyu, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn.

Awọn meji to ku ni Ahmed Shittu, ẹni ọdun mejidinlaaadọta ti wọn lo n ṣiṣẹ dẹrẹba, wọn ni mọto ẹ lawọn ọmọ ẹgbẹ ẹ fi maa n ṣọṣẹ buruku wọn, ati Zainab Nurudeen, obinrin loun ni tiẹ, ẹni ogun ọdun pere ni, oun ni wọn maa n ran lọọ ra awọn nnkan ija oloro ti wọn n lo.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko sọ nipa iṣẹlẹ yii lọfiisi rẹ n’Ikẹja lọjọ Aiku, CP Hakeem Odumosu ni lati afẹmọju lawọn ọlọpaa ti n wa gbogbo ibuba awọn afurasi yii, kọwọ too tẹ awọn meje yii ni nnkan bii aago meji ọsan.

Sibẹ, awọn kan ṣi raaye sa lọ nigba ti wọn kẹẹfin awọn agbofinro, ṣugbọn gbogbo wọn pata lawọn maa wa lawari nibikibi ti wọn ba sa si.

Lara awọn nnkan ija ti wọn ka mọ wọn lọwọ ni aake ati ada, ọpọlọpọ oogun abẹnugọngọ, egboogi oloro, ọti lile ati bọọsi alawọ ewe ti nọmba rẹ jẹ LAGOS APP 600 XA ti wọn lawọn afurasi naa fi n gbe ara wọn kiri igboro.

Ṣa, Odumosu loun ti ni ki wọn ko awọn tọwọ tẹ yii lọ si Panti, ni Yaba, ibẹ lawọn ọtẹlẹmuyẹ yoo ti tubọ wadii ọrọ lẹnu wọn, ki wọn too sin wọn dele-ẹjọ lati lọọ ṣalaye ara wọn.

Leave a Reply