Ọlọpaa yinbọn pa meji ninu awọn ajinigbe ti wọn fẹẹ ṣọṣẹ n’Itori

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ọjọ Aiku, Sannde ọsẹ yii, ti i ṣe ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ni awọn ajinigbe meji kan ku ni tiwọn, iyẹn lasiko ti awọn pẹlu ọlọpaa wọya ija lagbegbe Itori, nijọba ibilẹ Ewekoro, nipinlẹ Ogun.

Nnkan bii aago meje aabọ aarọ ni lọjọ Sannde naa lawọn ajinigbe ọhun ti wọn dihamọra, ti wọn tun fi ibomu (nose mask) bo imu atẹnu wọn pinpin, bẹrẹ si i dọdẹ adugbo naa, nitosi Poli ICT, n’Itori.

Ohun ti awọn ọlọpaa gbọ ree ti wọn fi lọ sibẹ, paapaa bo ṣe jẹ pe akọsilẹ iṣẹlẹ ijinigbe lagbegbe naa ti wa lọdọ awọn ọlọpaa Ewekoro tẹlẹ. Kia ni wọn gba ibẹ lọ gẹgẹ bi Alukoro wọn, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe sọ.

Ṣugbọn bawọn ajinigbe naa ṣe ri awọn ọlọpaa ni wọn bẹrẹ si i yinbọn mọ wọn, o to ogoji iṣẹju ti wọn fi n yinbọn mọra wọn gẹgẹ bi alaye Oyeyẹmi. Lasiko ti wọn n yinbọn naa ni awọn agbofinro pa meji ninu awọn ajinigbe ọhun, ti awọn yooku wọn si sa wọgbo lọ pẹlu ọta ibọn to ba wọn.

Awọn nnkan tawọn ọlọpaa ri gba lọwọ wọn ni: Ibọn ibilẹ kan, ọta ibọn meji ti wọn ko ti i yin, aake meji, kinni ti wọn n ko ọta ibọn AK47 si, foonu Android mẹta, foonu kekere meji, bata silipaasi mẹjọ ati baagi awọn ọmọọlewe meji.

Bi awọn ajinigbe ko ba yee wa sipinlẹ Ogun, CP Edward Ajogun ti i ṣe kọmiṣanna ọlọpaa ibẹ naa ni kọmandi oun ko ni i yee wọn i mu balẹ nikọọkan.

Leave a Reply