Ọlọpaa yinbọn pa ọlọkada l’Abule-Egba

Monisọla Saka

Rogbodiyan bẹ silẹ nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, nitori bi wọn ṣe ni awọn agbofinro kan yinbọn lu ọlọkada kan, ti wọn si pada gbe oku ẹ lọ gẹgẹ bi akọroyin PUNCH ṣe ṣalaye iṣẹlẹ naa.

Iṣẹlẹ ọhun ni wọn lo waye laduugbo Ọlayiwọla, nikorita Club Junction, Abule Ẹgba, nipinlẹ Eko, ni nnkan bii aago mẹfa aabọ irọlẹ.

ALAROYE gbọ pe niṣe lawọn ọlọpaa wọ oku naa lọ lẹyin ti iṣẹlẹ naa waye.

“Wọn n ju okuta mọ awọn ọlọpaa yẹn ni ki wọn too lọ”.

Ninu fidio ti akọroyin naa gba ni ẹjẹ ti ṣe balabala nilẹẹlẹ, bẹẹ lawọn eeyan n gbarata nitori idarudapọ ṣi wa lagbegbe naa.

Alaye ti ọga ọlọpaa teṣan Oko Ọba ṣe nigba ti wọn kan si i ni pe oun ko gbọ si iṣẹlẹ naa. O ni,” Ti wọn ba ni awọn ọlọpaa kan ni wọn ṣiṣẹ ibi yẹn, ṣe wọn ni DPO ọga ọlọpaa lo yinbọn ni? Emi o gbọ si i o”.

Ọga ọlọpaa yii lo waa dari akọroyin naa si ọdọ Agbẹnusọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin. Oun lo pada fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni ṣugbọn oun o ti i gbọ hulẹhulẹ ọrọ naa daadaa.

O ni, “Mi o ti i gbọ okodoro ọrọ naa, loootọ ni mo gbọ pe nnkan ṣẹlẹ, ṣugbọn mi o ti i gbọ hulẹhulẹ rẹ”.

Leave a Reply