Adewumi Adegoke
Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, igbakeji olori ileegbimọ aṣofin Naijiria nigba kan, Sẹnetọ Ike Ekerermadu, yoo pẹ lọgba ẹwọn awọn oyinbo ni London o, nitori ko jọ pe wọn ṣetan lati fi i silẹ kiakia. Ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni wọn ti mu ọkunrin naa ati iyawo rẹ bi wọn ti n gunle si papakọ-ofurufu Heathrow, niluu naa. Nigba ti won si fi iyawo rẹ silẹ lẹyin ọjọ meloo kan, wọn ko foun silẹ. Ọsẹ yii ni gbogbo eeyan ti ro pe yoo jade nibẹ, ṣugbon lọjọ Aje, ọjọ keje, oṣu yii, niṣe ni wọn ni ko ṣi wa lẹwọn nibẹ titi di ipari oṣu Kin-in-ni, ọdun 2023 to n bọ.
Ẹsun ti wọn fi kan Ekeremadu ni pe o mu ọmọkunrin kan wọ London lati lo kindinrin e lọna ti ko bofin mu. Ara Sonia, ọmọ Ekerermadu, ni ko ya, kindinrin ẹ lo bajẹ, wọn si ni ko too le gbadun, afi ki wọn rẹni ti yoo fi kindinrin rẹ tọrẹ fun un. Eyi ni ọga awọn aṣofin naa gbiyanju lati ṣe, toun pẹlu iyawo rẹ si mu ọmọkunrin akuṣẹẹ kan lọ si London pe ki wọn lo kindinrin ẹ fọmọ wọn, ti wọn si wa dokita, Obinna Obeta, ti yoo ṣeto naa lọhun-un paapaapaa!
Ṣugbọn ijọba awọn oyinbo ni ọna ti wọn tọ ko bofin mu, wọn si ṣọ́ Ekeremadu ati iyawo rẹ titi ti wọn fi ri wọn mu, lẹyin naa ni won mu Dokita Obeta to fẹẹ yọ kindinrin onikindinrin yii, wọn si la oun naa mọ itimọle. Ni bayii, wọn ti mu ọmọ rẹ naa, Sonia, iyẹn si ti foju ba ile-ẹjọ lọjọ Aje yii. Wọn fẹsun kan oun naa pe o ṣeto lati gbe eeyan wọ UK lọna ti ko bofin mu, ile-ẹjọ si gba beeli rẹ pe ko maa lọ na, ki igbẹjọ too bẹrẹ.
Ṣugbọn lati inu oṣu Kẹfa yii, itimọle ni Ekeremadu wa, wọn ko fi i silẹ. Ki i ṣe pe ẹsun ti wọn fi kan an ko ṣee gba beeli rẹ, o ṣee ṣe ko jẹ nitori awọn eeyan nla ọmọ Naijiria ti wọn ti mu bẹẹ ni London, ti wọn gba beeli wọn, ṣugbọn to jẹ niṣe ni wọn sa lọ ni wọn ko ṣe fọkuknrin naa silẹ.
Ohun ti wọn kọkọ sọ tẹlẹ ni pe wọn yoo bẹrẹ ẹjọ naa loṣu to lọ lọhun-un, wọn yoo si pari ẹ kia. Awọn ọ̀̀lọpaa lo ni awọn ko ti i pari awọn iwadii awọn, nitori ẹ ni wọn ṣe sun ẹjọ si ipari osu Kin-in-ni, ọdun to n bọ, ti wọn yoo si ṣe e titi wọ inu oṣu Keji. A gbọ pe awọn alagbara ni Naijiria, paapaa awọn aṣaaju nileegbimo aṣofin, ti lo gbogbo agbara wọn lati ri i pe wọn gba Ekeremadu jade lọgba ẹwọn ni London, ṣugbon kinni naa ko ṣee ṣe fun wọn. Tabi-ṣugbọn ko si si pe olori aṣofin tẹlẹ yii ti ha sọgba ẹwọn ni London, ọjọ ti wọn ba fi i silẹ lo ku.