Olori awọn aṣofin Eko gbaṣẹ lọwọ awọn amugbalẹgbẹẹ rẹ mẹrin

Faith Adebọla, Eko

 

Olori ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko, Ọnarebu Mudashiru Ọbasa, ti juwe ile fun mẹrin lara awọn oṣiṣẹ rẹ, Ọgbẹni Saka Fafunmi, Tọlani Abati, Dayọ Famakinwa ati Ọladimeji Oriyọmi.

Ninu lẹta ti aṣofin yii buwọ lu funra rẹ ti wọn kọ ni ọjọ kọkanla, oṣu ki-in-ni, si ọkọọkan awọn tọrọ kan, Ọbasa sọ pe loju-ẹsẹ ti wọn gba lẹta naa ni ki wọn fipo silẹ.

Inu oṣu kejila, ọdun 2019, ni Ọgbẹni Saka Fafunmi gbaṣẹ gẹgẹ bii olori awọn oṣiṣẹ lọfiisi abẹnugan awọn aṣofin naa, o si ti figba kan jẹ aṣofin nileegbimọ ọhun fun ọdun mejila gbako, to ṣoju awọn eeyan agbegbe Ifakọ-Ijaye.

Ni ti Ọgbẹni Tọlani Abati, oun ni akọwe agba feto iroyin lọfiisi olori awọn asọfin.

Oludamọran pataki fun Ọbasa lori ọrọ oṣelu ni Dayọ Famakinwa, oun naa si ti figba kan jẹ aṣofin to ṣoju agbegbe Ajeromi Ifẹlofun nile aṣofin ọhun.

Ẹni kẹrin tọrọ naa kan ni Ọgbẹni Ọladimeji Oriyọmi, oun ni oludamọran pataki fun Abẹnugan lori iṣẹ iwadii.

Akọroyin wa ba Ọgbẹni Abati sọrọ lori aago rẹ, o si fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni lẹta ti wọn fun oun ko sọ pato boya oun dẹṣẹ kan, wọn kan sọ pe iṣẹ ti tan ni. Ohun kan naa ni Saka Fafunmi sọ nigba ta a kan si i lori aago rẹ.

Oṣiṣẹ kan lọfiisi Abẹnugan to ba wa sọrọ sọ pe ijọba ipinlẹ Eko lo gbaṣẹ lọwọ awọn mẹrẹẹrin, ki i ṣe Ọbasa, tori ijọba Eko lo gba wọn siṣẹ, ijọba lo n sanwo oṣu fun wọn.

Wọn ni Ọbasa yoo kede awọn to maa rọpo wọn laipẹ.

Attachments area

Leave a Reply