Olori awọn aṣofin tẹlẹ, Yakubu Dogara, ti tun kuro ninu PDP, o ti pada si APC

Ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ni olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin tẹle, Yakubu Dogara, kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP to ti wa lati ọdun to kọja, to si pada sinu ẹgbẹ oṣelu APC.

Dogara gbe igbesẹ yii lẹyin ti oun ati Gomina ipinlẹ Yobe to tun jẹ alaga igbimọ alaamojuto ẹgbẹ APC, Mala Buni, ṣabẹwo si Aarẹ Buhari nileejọba.

Ọdun to kọja ni ọkunrin to n ṣoju awọn eeyan agbegbe Bogoro/Das/Tafawa Balewa Constituency, nipinlẹ Bauchi yii, kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC to ti wa tẹlẹ, to si dara pọ mọ PDP. Inu ẹgbẹ naa lo ti dije dupo gẹgẹ bii ọmọ ileegbimọ aṣoju-ṣofun, to si wọle.

Iyalẹnu lo jẹ fun awọn ololufẹ rẹ atawon ọmọ ẹgbẹ PDP pe ọkunrin naa ti fii wọn silẹ ninu ẹgbẹ naa. Bo tilẹ jẹ pe ko sọ idi pataki to fa igbesẹ to gbe yii.

Leave a Reply