Olori ẹgbẹ Boko Haram meji ti sọrẹnda fawọn ọmọ ogun ilẹ wa

Adeoye Adewale

Meji lara awọn ọga ẹgbẹ Boko-Haram kan ti wọn n yọ awọn eeyan agbegbe Sambisa, nijọba ibilẹ Bama, nipinlẹ Borno, lẹnu nigba gbogbo ti juwọ silẹ patapata fawọn ọmọ ogun orileede wa pe awọn ko ja mọ rara. Awọn meji ọhun ni, Khaid Malam Ali ati igbakeji rẹ, Bunu Umar.

ALAROYE gbọ pe ija itajẹsilẹ nla kan to waye laarin ikọ ẹgbẹ Boko-Haram ti Malam Ali n dari rẹ ati ẹgbẹ afẹmiṣofo mi-in ti wọn n pe ni ‘Islamic State Of West African Province’ ISWAP, nibi ti ikọ ISWAP ti pa ọpọ lara awọn ọmọ ẹgbẹ ti Ali n dari lo mu ki ọkunrin naa juwọ silẹ fun ikọ awọn omọ ogun orileede wa pe ki wọn faaye gba awọn lati maa gbe igbe alaafia laarin ilu bayii.

Ohun ta a gbọ ni pe ija agba meji kan bẹ silẹ laarin ikọ Boko Haram ati  ISWAP, ti apa awọn ti ISWAP si ka tawọn akatako wọn yii, ọpọ lara awọn ọmọ ogun rẹ lo si ba ija naa lọ. Bakan naa ni ikọ ISWAP ko da awọn obinrin wọn si rara, afi bii ẹni pe wọn fẹẹ pa gbogbo ohun to jẹ ti ikọ Boko Haram ti Malam Ali n dari run patapata.

Wọn ni ki ọkunrin afẹmiṣofo yii too juwọ silẹ, ko sẹnikan to jẹ fọwọ pa ida rẹ loju lagbegbe naa, niṣe lo maa n ṣe bo ti wu u laarin ilu.

Leave a Reply