Olori ilegbimọ aṣofin agba, Lawan, ti ja bọ o

Faith Adebọla

Ile-ẹjọ giga apapọ kan to fikalẹ siluu Damaturu, nipinlẹ Yobe, ti gbegi dina fun erongba Olori awọn aṣofin apapọ ilẹ wa, Sẹnetọ Ahmed Lawan, lati pada sile aṣofin naa lọdun to n bọ, latari bi wọn ṣe paṣẹ pe Ọgbẹni Bashir Machina ni ojulowo oludije funpo sẹnetọ ẹkun idibo Ariwa ipinlẹ naa, wọn ni ki Lawan lọọ jokoo ara ẹ jẹẹ.

Bakan naa nile-ẹjọ tun paṣẹ fun ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, pe ki wọn tete lọọ fi orukọ Machina sakọọlẹ wọn gẹgẹ bii oludije funpo sẹnetọ, ki wọn si fun un niwee-ẹri gẹgẹ bii ojulowo oludije nibaamu pẹlu ilana ati eto ajọ naa.

Adajọ Fadima Aminu paṣẹ yii l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2022.

Fadima ni lẹyin toun ti wo gbogbo atotonu ati awijare olujẹjọ ati olupẹjọ, toun si ti wo gbogbo nnkan to yi eto idibo abẹle ẹgbẹ APC nipinlẹ Yobe po, ko si kọnu-n-kọhọ kankan ninu eto idibo abẹle wọn to waye lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Karun-un, to kọja, o lo ṣe kedere pe Machina ni ẹni tawọn oludibo yan, ati pe ko si bi orukọ Lawan ṣe le wa lara awọn to n ja funpo naa, tori ko si lara awọn oludije funpo sẹnetọ lasiko idibo.

Ṣe lọjọ Aje, Mọnde to ṣaaju, lasiko to ye ki idajọ ti waye, niṣe ladajọ naa paṣẹ lati sun idajọ rẹ siwaju nigba tawọn lọọya ni iha mejeeji na mọ ara wọn ni kootu, ti ariyanjiyan nla si bẹrẹ.

Tẹ o ba gbagbe, Machina ni wọn kọkọ kede orukọ rẹ nibi eto idibo abẹlẹ naa gẹgẹ bii oludije wọn, ṣugbọn lẹyin ti Lawan ti lọọ dije funpo aarẹ ti ko si wọle, to jẹ niṣe lo lulẹ, o loun ni ki wọn tun mu bii oludije funpo sẹnetọ, bẹẹ saa maarun-un lo ti lo nipo aṣofin apapọ ọhun. Ọsẹ diẹ sẹyin ni Alaga apapọ ẹgbẹ APC, Abdullahi Adamu, sọ pe Lawan lawọn maa fa kalẹ.

Ko ti i daju boya Lawan yoo gba kamu abi yoo pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun.

Leave a Reply