Olori kẹfa yoo wọ aafin Ọọni Ogunwusi lọjọ Aje

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ẹni nla naa lo n ṣe nnkan nla, l’ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹwaa yii, ni iyawo ọṣingin mi-in yoo tun wọ aafin Adimula, Ọọni Ogunwusi. Ni yoo ba di iyawo kẹfa to wọle kabiyesi laarin oṣu meji sira wọn.

Ninu ikede kan ti Akọwe iroyin kabiyesi gbe si ori ikanni rẹ lo ti kede pe obinrin mi-in, iyẹn Temitọpẹ Adeṣẹgun, yoo tun di olori laafin ọba. Ọmọ bibi ilu Ijẹbu-Ode ni wọn pe arẹwa obinrin naa, ọmọọba si loun naa pẹlu.

Ninu ọrọ ti Adefare kọ sori ikanni fasibuuku rẹ ọhun lo ti ni ‘ Olori Temitọpẹ Adesẹgun Ogunwusi, ọmọọba n’Ijẹbu, to tun jẹ Olori n’Ileefẹ, ọla ni ọjọ ayẹyẹ.’

Tẹ o ba gbagbe, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ogunjọ, oṣu Kẹwaa yii. Ni ayaba tuntun mi-in wọ aafin, iyẹn Aderonkẹ to jẹ ọmọọba ni ila Ọba Ademiluyi ti i ṣe Ọọni Ifẹ kejidinlaaadọta, lati agboole Otutu, niluu Ileefẹ, to si kawe-gboye ninu imọ ofin.

Oun ni alakooso ileeṣẹ nla kan ti wọn ti n ṣe adirẹ niluu Ileefẹ, iyẹn Adire Textile Production Hub, ileeṣẹ ti Ọọni Ogunwusi da silẹ lọdun to kọja.

Olori tuntun yii tun ni alakooso eto omidan arẹwa ọlọdọọdun ti wọn maa n ṣe, iyẹn Moremi Ajanṣoro Beauty Pageant.

Oun ni iyawo karun-un ti Ọọni Ogunwusi fẹ wọ aafin laarin oṣu kẹsan-an ọdun yii si’Kẹwaa yii.

Ibẹrẹ oṣu Kẹsan-an ọhun, iyẹn ni nnkan bii oṣu mẹsan-an ti Olori Naomi Ṣilẹkunọla, Iya Tadenikawo, ọmọ bibi ilu Akurẹ, ko jade laafin, ti wọn o si ri ọrọ naa yanju di ba a ṣe n sọ yii, ni Mariam Anako to jẹ ọmọ bibi Ẹbira, nipinlẹ Kogi, wọle tilu-tifọn gẹgẹ bii ayaba tuntun ti wọn fi ṣọdun Ọlọjọ to kọja lọ.

Lẹyin eyi ni wọn tọrọ Elizabeth Ọpẹoluwa Akinmuda ati Oluwatobilọba Abigail Philipps, tawọn mejeeji si di olori.

Ọsẹ to lọ lọhun-un ni adumaadan orekelẹwa Afọlaṣade Ashley Adegoke di ayaba tuntun.

Ni bayii, ọmọọba mi-in ti tun feẹ di ayaba, oun naa si ni Temitọpẹ ti yoo wọle Ọọni lọjọ Aje.

Leave a Reply