Olori oṣiṣẹ Gomina Zulum tipinlẹ Borno jade laye

Olori oṣiṣẹ Gomina Babagana Zulum tipinlẹ Borno, Babagana Wakil, ti jade laye.

Wakil lo jẹ Ọlọrun nipe laaarọ oni, Ọjọbọ, Wẹsidee.

Gẹgẹ bi Isa Gusau to jẹ alukoro gomina ṣe sọ, aago mẹrin irọlẹ oni ni oloogbe naa wọ kaa ilẹ ni Shehuri North, niluu Maiduguri to jẹ olu-ilu ipinlẹ Borno.

Ọdun kan pere ni Wakil fi wa nipo olori oṣiṣẹ gomina ki iku too pa oju ẹ de.

Leave a Reply