Olori ọmọ-ogun ofurufu fi gbedeke le ogun Boko Haram

Olori awọn ọmọ-ogun ofurufu nilẹ yii, Ọgagun Sadique Abubakar, ti ṣeleri pe opin ọdun yii ni ogun Boko Haram yoo wa sopin.

Abubakar sọrọ ọhun niluu Maiduguri lonii, ọjọ Abamẹta, Satide, lasiko to n ba awọn ikọ ofurufu to n koju awọn Boko Haram, Air Task Force of Operation Lafiya Dole, sọrọ.

Ọgagun naa ni awọn ko ni i gba ki ẹnikẹni tabi ẹgbẹ kankan foju tẹmbẹlu agbara ti Naijiria ni lati di gbogbo ilẹ rẹ mu ṣinṣin, asiko si ti to lati fi ye awọn ọmọ ikọ apanijaye Boko Haram pe ko saaye rẹdẹrẹdẹ mọ.

Abubakar ni o pẹ tan, opin ọdun yii ni ikọ naa yoo pari iṣẹ ti wọn fun wọn lati fopin si ọrọ ogun naa, bẹẹ ni ijọba apapọ ti pese awọn irinṣẹ ogun ti yoo mu iṣẹ ọhun rọrun.

Ọdun 2002 ni ikọ Boko Haram bẹrẹ, ṣugbọn lẹyin tọwọ tẹ olori wọn, Mohammed Yusuf, to si ku sọdọ ijọba lọdun 2009 ni wọn di ikọ gbẹmi-gbẹmi. Laarin asiko naa si ọdun yii, ẹgbẹlẹgbẹ ẹmi lo ti sọnu nipasẹ wọn, bẹẹ lawọn to le ni miliọnu meji di alainilelori.

Leave a Reply