Monisọla Saka
Ajọ to n mojuto nnkan jijẹ, oogun ati ohun mimu nilẹ wa, National Agency for Food and Drug Administration and Control (NAFDAC), pẹlu ifọwọsowọpọ awọn ọmọ ogun ilẹ Naijiria, Nigerian Army 15 Field Engineering Regiment, to wa ni Badagry, nipinlẹ Eko, ti fi panpẹ ofin gbe afurasi ọdaran kan, Ọgbẹni Chinedu Okafor, to n pọn ayederu ọti, to si n ta afawọn araalu bii ojulowo.
Inu ile ti ọkunrin yii n gbe to wa ni Nọmba 24, MTN Road, Badagry, nipinlẹ Eko, ni wọn ni o fi ṣe ileeṣẹ to ti n pọn ọti lile loriṣiiriṣii. Eyi lo mu ajọ NAFDAC atawọn ṣọja ọhun lọ sibẹ, ti wọn si ti ileeṣẹ naa pa lẹyin ti wọn fi panpẹ ofin gbe ọkunrin naa.
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni ajọ NAFDAC sọrọ yii di mimọ. Wọn ni awọn ṣọja yii ni kurukẹrẹ iṣẹ buruku Chinedu fu lara, ti aṣiri ẹ fi tu.
Ninu atẹjade ti wọn fi sita ni wọn ti ni, “Awọn oṣiṣẹ NAFDAC, ti ileeṣẹ ologun ẹka 15 Field Engineering Regiment, to wa ni Badagry, kun lọwọ, ti dawọ iṣẹ Ọgbẹni Chinedu Okafor, to yan ayederu ọti ṣiṣe laayo, eyi to n ṣe ninu ile ẹ to wa ni Ojule kẹrinlelogun, MTN Road, Badagry, duro.
“Awọn ileeṣẹ ologun ni ara fu wọn si iṣẹ ti ko bofin mu tọkunrin yii n ṣe, eyi lo si ṣokunfa bi wọn ṣe lọ sile rẹ, ti wọn si ba ọpọlọpọ ayederu ọti to ti ṣe atawọn eroja to fi n ṣe wọn, ni wọn ba nawọ gan an, ti wọn si fa a le awọn oṣiṣẹ ajọ NAFDAC ti wọn wa ni Ports Inspection Directorate, ẹnubode Sẹmẹ, Badagry, nipinlẹ Eko, lọwọ.
“Lasiko ti wọn yọju sibi to n lo fi pọn ọti yii ni wọn ko gbogbo awọn ohun eelo to fi n pọn ayederu ọti yii atawọn ọja to ti ṣe silẹ, ti wọn si ti ileeṣẹ rẹ ọhun pa.
Iwadii ta a ṣe fidi ẹ mulẹ pe nitori bi ọjọ ṣe ti pẹ ti Okafor ti n taja ti ko bofin mu yii, o ti ba ọja ọti jẹ lagbegbe Badagry”.
Gbogbo ọja ti wọn ri ko nileeṣẹ afurasi, eyi to n lọ bii aadọta miliọnu Naira (50,000,000), ni wọn ni awọn yoo bajẹ, lẹyin naa ni wọn yoo foju rẹ bale ẹjọ.
Bakan naa ni ajọ NAFDAC rọ awọn araalu lati maa kiyesara, ki wọn si fẹjọ ohunkohun to ba mu ifura dani ti wọn ba ri laduugbo wọn sun awọn alaṣẹ to ba wa nitosi wọn.