Ọlọrun lo paṣẹ fun mi pe ki n lọ seti okun nihooho lati gbadura fun Aṣiwaju-Ọlaiya Igwe

Jọkẹ Amori

Ọrọ bi ọkan ninu awọn oṣere ilẹ wa, Ẹbun Oloyede ti gbogbo eeyan mọ si Igwe ṣe lọ si eti okun, to si lọọ gbadura fun oludije funpo aarẹ lorukọ ẹgbẹ APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, nihooho ọmọluabi  ko ti i rodo lọọ mumi o, niṣe lo n ran bii ina ọyẹ.

Ọkunrin ọmọ bibi ilu Abẹokuta ti wọn tun maa n pe ni Ọlọlade Mr Money naa ti tun jade sita o, o si ti sọ idi to fi ṣe ohun to ṣe naa. O ni ariran ni oun, Ọlọrun maa n fi iran han oun gidigidi, ati pe Ọlọrun lo paṣẹ fun oun pe ki oun rin nihooho ni eti okun ki oun fi gbadura fun Aṣiwaju Bọla Tinubu.

Oṣere naa salaye yii lasiko ti ileeṣẹ tẹlifiṣan TVC to jẹ ti Aṣiwaju Bọla Tinubu gba a lalejo lori eto kan ti won maa n pe ni ’Ero tirẹ’ iyẹn ‘Your View’ pe, ‘Mo wa lati ṣalaye nipa ohun ti mo ṣe ni bii ọjọ mẹrin sẹyin ni, mi o wa lati tọrọ aforiji lọwọ ẹnikẹni, ṣugbọn mo kan fẹ ki awọn eeyan mọ idi ti mo ṣe ṣe ohun ti mo ṣe ni. Bọla Tinubu ti ṣe ohun ribiribi laye mi, mo ti sọ ọ ni aimọye igba ninu awọn ifọrọwerọ ti mo ti ṣe sẹyin. Niṣe ni wọn sọ fun mi pe ki n dide, ki n lọọ ṣe ohun ti mo ṣe yii ninu ẹmi’.

Ọlaiya ni, ‘‘Arina ni mi, Ọlọrun fun mi lẹbun irina gan-an. Ọpọ igba ni Ọlọrun ti maa n fi ohun to ni fun mi ti yoo ṣẹlẹ han mi siwaju asiko ti yoo ṣẹlẹ. Oju oorun ni mo wa lọjọ yii ti mo fi gbọ ohun Ọlọrun pe, ‘Jọwọ, dide, o sọ pe o nifẹẹ Aṣiwaju, o si ti n ran ọ lọwọ’, mo ni bẹẹ ni. ‘O ya, dide, lọọ ṣe awọn nnkan bayii bayii bayii fun un. Lọ si eti okun, ki o si lọọ gbadura fun Aṣiwaju’ Mo mọ-ọn-mọ ya aworan fidio naa fun gbogbo aye lati ri ni.

‘‘Oṣere ni mi, mo si tun jẹ oloṣelu lẹgbẹẹ kan, mo waa so pe gẹgẹ bii oṣere, mo le ṣe e, ṣugbọn mo tun gbọdọ ronu nipa awọn ẹbi mi. Ṣugbọn mo fẹẹ sọ ohun kan fun yin o, ko si ohun ti mi o le ṣe lati fi atilẹyin mi han si Aṣiwaju, niwọn igba ti mo mọ pe ohun ti mo fẹẹ ṣe yii ko ni nnkan kan an ṣẹ pẹlu ẹnikẹni, mo le ṣe e de ayekaaye’’.

Nigba ti awọn to n ṣeto yii beere bi fidio naa ṣe dori ẹrọ ayelujara, Ọlaiya ṣalaye pe, ‘‘Bi ẹ ba jẹYoruba, babalawo le sọ pe ti o ba fẹẹ ṣe iru adura bayii, ri i pe o lọ si oriṣiiriṣii ọja, lọjọ ọja ni ko o gbe ẹbọ, ọpọlọpọ eeyan yoo si wa nibẹ. Ko siyatọ ninu ohun ti babalawo maa n ni ki eeyan ṣe lọja yii ati ohun ti mo ṣe. Mo mọ-ọn-mọ ka fidio naa silẹ fun awọn eeyan lati ri ni. Ki i ṣe nitori owo rara. Mo mọ ọn mọ gbe e sori afẹfẹ ni nitori mo tẹti si ohun to ran mi, mi o si kabaamọ rara pe mo ṣe e’’.

Nigba ti atọkun bi Ọlaiya pe ṣe o ro pe ohun ti oun ṣe yii mu eeso rere to fẹ ko mu wa, abi bawo lo ṣe ri loju rẹ, Ọlaiya ni, ‘‘Nigba ti mo wa nileewe giga fasiti lẹnu ọjọ mẹta yii, abala ẹkọ kan wa ti wọn kọ wa ti wọn pe ni ‘eyi wu mi o wu ọ’ (individual diferences) niwọn igba ti mo n ṣe ohun ti mo ṣe, ti ko si ṣakoba fun ẹnikẹni, ko si ẹṣẹ nibẹ.

‘‘Ẹja nla nla ni Aṣiwaju Ahmed Tinubu jẹ ninu aye mi, mo si mọ pe laipẹ laijinna, yoo di aarẹ orileede yii’’.

Ngba ti wọn n pe akiyesi Ọlaiya si i pe awokọṣe lo jẹ fun awọn eeyan, paapaa ju lọ awọn ololufẹ rẹ, ati pe oju ọtọọto ni awọn eeyan fi wo ohun to ṣe yii. Wọn ni awọn kan n sọ pe ṣe ka ri mi lo fi fidio naa ṣe, tabi nitori asiko oṣelu to jẹ, ki wọn le ranti rẹ to ba ya. Ṣugbọn Ọlaiya ni ki ṣe nitori eleyii, o ni ki i ṣe igba akọkọ ree, o ni aimọye igba lohun ti sọ ohun ti ọkunrin naa ṣe ninu aye oun fun awọn eeyan, ki i ṣe nitori oṣelu tabi pe eto ibo n bọ. ‘‘Ohunkohun ti ẹnikẹni le sọ, ipinnu mi ni, mo ṣe e fun Aṣiwaju. Mi o fi nnkan ọmọkunrin mi han, idi mi lẹyin nikan ni wọn ri. Mi o fi ohun ti awọn eeyan n reti pe wọn maa ri han, kamẹra ko ṣe afihan rẹ.

‘Ọpọ awọn to n sọrọ si mi jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu alatako atawọn ti wọn n ṣe Yoruba Na… (ko daruko rẹ tan) ohun ti wọn ri ki wọn pe e ni wọn n sọrọ nipa fidio naa’.

Nigba ti awọn atọkun beere lọwọ rẹ pe o da bii pe ẹru n ba a bo ṣe ṣe fidio naa pe o ṣee ṣe ki Aṣiwaju ma wọle lo fi n bẹ Ọlọrun bẹẹ. Ọlaiya ni Ọlọrun ko ni i ran oun ni iṣẹ ti i ko ni i wa si imuṣẹ. O ni ki awọn eeyan gba ohun gbọ, Tinubu yoo di aarẹ Naijiria laipẹ.

Nigba ti wọn beere pe ṣe awọn eeyan Aṣiwaju ti ri i, ṣe wọn ti pe e, wọn ti ba a sọrọ, o ni ki wọn ma bi oun ni ibeere yii, o ni ọrọ to kan oun nikan ni eyi.

Nigba ti awọn atọkun tun bi i pe njẹ igbesẹ to gbe naa ni ọna kan ṣoṣo to fi le fi ẹmi imoore rẹ han si Tinubu. Ọlaiya ni, eyi wu mi o wu ọ ni. O ni eyi wu mi o wu ọ ni ọrọ naa. Ohun ti oun le ṣe, ẹlomi-in le ma le ṣe e, ohun ti ẹlomi-in naa le ṣe, oun le ma le ṣe e. O fi kun un pe oja kan ni Aṣiwaju, oun gẹgẹ bii ẹni to fẹẹ polowo oja naa le ta a ni ọna ti oun ba fẹ, boya nipa ti ara ni tabi nipa ti ẹmi. Ọlaiya ni ko si ọna ti oun ko le gba lati ṣatilẹyin fun Aṣiwaju.

Nigba ti wọn beere boya Islaamu fọwọ si ohun to ṣe naa, o ni ọrọ ẹmi ni, nitori oun gbọ ohun kan ni oun fi ṣe ohun ti oun ṣe.

Nigba ti wọn bi i boya igbesẹ to fẹẹ gbe naa ko ni i ṣakoba fun un, o ni ko le ṣe akoba fun oun, nitori lẹyin rẹ ni ileesẹ kan fi oun ṣe aṣoju.

Leave a Reply