Faith Adebọla
‘‘Afi suuru gan-an ni ọrọ ijọba ilẹ Naijiria ti wọn lọọ mu Sunday Igboho ni orileede Benin. A ti mọ pe wọn maa mu un. Ṣugbọn kin ni ọmọkunrin naa ṣe fun wọn. Nitori pe o ni ki wọn yee pa awọn ọmọ Yoruba, to si lọọ doju ija kọ awọn Fulani ni Igbo-Ọra. Gbogbo wa la mọ pe nitori ominira Yoruba ati nitori awọn Fulani ni ijọba Buhari fi n gbogun ti Sunday Igboho, ko ṣẹ wọn ni ẹṣẹ kankan ju bẹẹ lọ. Asiko niyi fun gbogbo ọmọ Yoruba lati ronu gidigidi.’’ Akowe eto ẹgbẹ Afẹnifẹre, Oloye Kọle Ọmọlolu lo sọrọ yii lasiko to n fi aidunnu rẹ han si bi awọn ọtẹlẹmuyẹ ṣe lọọ mu Sunday Igboho ni orileede Benin.
Nigba ti Ọmọlolu n ba ALAROYE sọrọ laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, o ṣalaye pe erongba ijọba ni pe bi awọn ba ti le mu Sunday Igboho, ẹru yoo ba awọn ọmọ Yoruba yooku, wọn aa si sa pada. Ṣugbọn ohun ti awọn ijọba yii ko mọ gẹgẹ bo ṣe sọ ni pe Sunday Igboho pọ rẹpẹtẹ to ṣi maa jade.
‘’Emi ti mo n ba yin sọrọ yii, Sunday Igboho ni mi, o kan jẹ pe ọna ti onikaluku n gba ja ija tirẹ yatọ si ara wọn ni. A ti ja iru ija yii aaye NADECO, a si bori, bẹẹ la tun maa bori wọn lasiko yii. Kinni kan to si da mi loju ni pe gbogbo awọn abiyamọ aye yoo duro ti Sunday Igboho, nnkan kan ko ni i ṣe e, bẹẹ ni yoo bọ ninu okun ti wọn dẹ silẹ fun un.
Nigba to n sọrọ lori ohun to ṣee ṣe ko ṣẹlẹ si ijangbara awọn eeyan fun ominira Yoruba pẹlu bi wọn ṣe mu Sunday Igboho yii, ọkan ninu awọn agba Afẹnifẹre naa ni Igbesẹ ti ijọba Buhari gbe yii lo maa fun awọn eeyan lokun lati tẹsiwaju ninu ijangbara ilẹ Yoruba. Wọn fẹẹ ma mu wa lẹru ni. Bẹẹ ni wọn si n fi Yoruba ṣere, pẹlu bi wọn ṣe n fi Yoruba ṣere yii, won ko fẹ ki Naijiria toro, nitori ko sijọba to fi Yoruba ṣere ti ko ri wahala. Nigba ti ina ba bẹrẹ si i jo awọn amunisin, wọn aa taji.
‘’Ọlọrun da Yoruba yatọ, wọn fẹẹ ba ilẹ Yoruba jẹ ni, ṣugbọn Ọlọrun ko ni i gba fun wọn. O da mi loju pe nnkan kan ko ni i ṣe Sunday Igboho, ẹmi rẹ yoo gun, yoo si jere awọn ọmọ pẹlu ọmọọmọ rẹ.
Awọn aṣaaju wa naa ti ni iru idojukọ yii. Ẹṣẹ aimọdi ni wọn tori rẹ ju Awolọwọ sẹwọn, ṣugbọn Ọlọrun ko o yọ. Bẹẹ naa ni wọn ṣe fun Baba Ọbasanjọ, nigba to pada de, o di aarẹ. Ọlọrun to ja fun Yoruba laye Abacha yoo ja fun wa lasiko yii.
Ki ijọba yii naa si maa ranti pe wọn ko ni i wa nibẹ titi lae, alagbaara to wa loni ko rọra ṣe, nitori agbara maa bọ si ọwọ ẹlomi-in lọla.