Ọlọrun yọ Kwankwaso, mi o ba fọ ọ leti ka ni mo ba a lọdọ Tinubu-Ganduje

Adewale Adeoye

Awọn agba bọ,wọn ni agba ki i wa lọja kori ọmọ tuntun wọ, owe yii gan-an ni olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ro papo, to fi tete gbe igbesẹ akin kan lati pana ija nla to n lọ lọwọ laarin gomina ipinlẹ Kano tẹlẹ, Alhaji Umar Ganduje, ati ondije dupo aarẹ orileede yii lẹgbẹ oṣelu NNPP, to tun ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ ọhun Enjinnia Rabiu Musa Kwankwaso.

Gbara ti Gomina Abba Yusuf to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣẹlu NNPP ti Kwankwaso ṣatilẹyin fun wọle sipo tan ni gomina ọhun ti n fọwọ lile mu Gandujẹ ni gbogbo ọna. Llara awọn ohun to ti ṣe fun un bayii lati fi han an pe oun yoo fiya nla jẹ ẹ ni bo ṣe n wo awọn ile olowopọọku atawọn ṣọọbu igbalode kan ti ijọba Gandujẹ kọ nigba iṣakooso rẹ, o ni ori ilẹ iọjba ni wọn kọ ọ si, ko si tọna. Igbesẹ yii ni Gandujẹ gbagbọ pe o lọwọ kan abosi ninu.

ALAROYE gbọ pe gbara ti Gomina Abba Yusuf depo tan lo ti paṣẹ pe ki awọn oṣiṣẹ ijọba kan maa da gbogbo awọn ile ati ṣọọbu ti ijọba kọ lasiko ijọba Ganduje lulẹ. Igbesẹ yii ni wọn lo bi Gandujẹ ninu gidi gan-an. Ọkunrin naa sọ pe ọna ti gọmina ọhun n gba lati wo awọn ṣọọbu atawọn ile naa ko bofin ipinlẹ naa mu rara, ṣugbọn ti gomina ọhun ko dawọ duro rara.

Ọrọ ọhun ti fẹẹ daja nla silẹ laarin awọn agba ọjẹ oloṣelu mejeeji yii. Eyi gan-an lo mu ki Aarẹ Tinubu pe ipade alaafia kan laarin awọn mejeeji siluu Abuja, lati ba wọn pari ija naa.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni Aarẹ pe awọn mejeeeji sọfiisi rẹ lati ba wọn pari rẹ, ṣugbọn Ganduje faake kọri pe oun ko ni i gba rara.

Loootọ awọn mejeeji ni wọn jọ de si Aso Rock fun ipade pataki ọhun gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ, ṣugbọn ọtọọtọ ni olori orilede yii ba wọn sọrọ lori ohun to n ṣẹlẹ naa.

Lẹyin ipade ti Ganduje ni pẹlu Aarẹ ti sọ pe oun mọ pe Kwankwaso wa nile ijọba nibẹ, ko kan jade si oun ni, ṣugbọn Ọlọrun lo yọ ọ pe oun ko foju kan an ni ọfiisi Tinubu lakooko ipade alaafia naa,  O ni ṣe loun iba lu u bajẹ, ni nitori ṣe ni inu rẹ n bi oun gidi. Ọkunrin naa ni gbogbo ile ati ṣọobu ti wọn kọ naa lo wa ni ibamu pelu ilana ati ofin.

Ṣa o, Gandujẹ ti sọ pe lara pe Gomina Abba Yusu n tẹle imọran odi ti Kwankwaso n gba a, ọpọ lara awọn araalu to nifẹẹ rẹ tẹlẹ ti n kọyin sijọba rẹ, ti ko si mọ.

Siwaju si i, Gandujẹ ni oun ti fọrọ wiwo awọn ile atawọn ṣoobu naa to ọga agba ọlọpaa orileede yii, Usam Alkali Baba, leti, oun si tun ti sọ fun Tinubu pẹlu.

Bakan naa lo sọ pe lara pe gomina ọhun ko gbe ọrọ naa gba ibi to yẹ lo mu ki ọkan lara awọn agbaṣẹṣe ti wọn kọ awọn ile atawọn ṣọọbu naa lakooko ijọba oun gbe e lọ si kootu bayii, ti wọn si n beere fun biliọnu mẹwaa Naira gẹgẹ bii owo itanran fun ohun ti gomina ọhun ṣe.

Bẹ o ba gbagbe, nigba ti Kwankwaso jẹ gomina ipinlẹ Kano, Ganduje yii ni igbakeji rẹ, ti ko si sija kankan laarin awọn mejeeji.

Leave a Reply