Olowo Eko, Ọba Rilwan Akiolu, ti pada saafin ẹ l’Ekoo

Tilu-tifọn ni Ọba ilu Eko, Alayeluwa Rilwan Akiolu, fi pada si aafin ẹ lọjọ ọdun tuntun lẹyin oṣu keji tawọn eria bọisi kan ti kọ lu u laafin ẹ, lasiko rogbodiyan SARS.

Lori ikanni abẹyẹfo ọkan lara awọn Oluranlọwọ gomina ipinlẹ Eko nipa eto ilera, ̀Ọrẹoluwa Finnih, lo ti kede ẹ pe Kabiesi ti pada si aafin.

Tilu pẹlu ijo pẹlu ibomu nimu ni awọn eeyan fi jo pade Ọba Rilwan Oṣuọlale si aafin ẹ, ni Iga Idunganran, nisalẹ Eko.

Tẹ o ba gbagbe, ọpẹlọpẹ awọn ṣọja ni wọn sare si baba naa lọjọ ti awọn janduku kan ya bo aafin ẹ lasiko ti rogbodiyan tawọn ọdọ n ṣe ta ko ajọ SARS bẹ silẹ lọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹwaa, ọdun to kọja.

Bi wọn ṣe ba dukia jẹ lọjọ naa, bẹẹ ni wọn gbe ọpa aṣẹ ọba lọ, ti aafin ọhun ko si ṣee sun mọ, nitori niṣe lawọn ọmọọta gba gbogbo inu ibẹ kan fun ọjọ meji gbako.

 

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Oṣere tiata yii pariwo: Ẹ gba mi o, latọjọ ti mo ti ṣojọọbi mi ni itẹkuu lawọn oku ti n yọ mi lẹnu

Monisọla Saka Kayeefi! Inu iboji larakunrin yii ti ṣe ọjọ ibi ẹ. Oṣerekunrin ilẹ Ghana …

Leave a Reply

//ashoupsu.com/4/4998019
%d bloggers like this: