Olowu ilẹ Owu naa ti waja o

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i kede rẹ faye gbọ, iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe Olowu tilẹ Owu, nipinlẹ Ogun, Ọba Adegboyega Dosunmu Amọroro Keji, ti dagbere faye.

Latigba ti hunrun hunrun pe Kabiyesi ti waja ti gba ilu kan ni awọn eeyan ti fẹẹ mọ baye ni Kabiyesi wa tabi ọba naa ti waja gẹgẹ bawọn kan ṣe n gbe e kiri.

Ohun ti ALAROYE gbọ lati ẹnu ẹnikan to jẹ wọle-wọde aafin Olowu ni pe Kabiyesi ti waja.

Ọkunrin naa sọ pe o ti pẹ gan-an to ti rẹ Olowu Adegboyega Dosunmu, ti baba naa ko jade.

O fi kun un pe ko ti i sẹni to fiṣẹ ran awọn lati tufọ ipapoda ọba nla nilẹ Owu naa ni kaluku ṣe ṣenu ni deede ṣibi. O ni awọn agbaagba to mọ nipa bi wọn ṣe n tufọ ọba ni yoo gbe iroyin naa jade to ba jẹ ootọ, bi wọn ko ba si ti i ṣe bẹẹ, ẹnikẹni ko gbọdọ kede ẹ, nitori lai ku ẹkiri, ko sẹni kan ti i fi awọ ẹ ṣe gbẹdu.

Awọn eeyan tun n reti atẹjade ibanikẹdun to yẹ ko ti ọwọ awọn eeyan bii Oloye Ọbasanjọ ti i ṣe Ẹbọra Owu wa, ṣugbọn Ọbasanjọ ko wi nnkan kan, bẹẹ ni ko si oloye Owu kan to sọ ohunkohun lori ibi ti Olowu Kanguere wa titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii.

Olowu, Ọba Adegboyega Dosunmu, Akọbi Oodua, Amiwo-Aja, bẹrẹ ileewe alakọọbẹrẹ ni Owu Baptist Day School, lọdun 1941, o si lọ sileewe Girama Baptist High School, Abẹokuta lọdun 1950.

Kabiyesi kawe l’Ekoo, o ka niluu oyinbo, o mọ nipa iṣẹ ere ori itage, oun lo si wa nidii agbekalẹ ere oniṣẹ ti wọn n pe ni ‘Village Headmaster’ ti wọn n ṣe laye ọjọun.

Ọdun 1976 ni Amọroro keji yii di alaga ijọba ibilẹ Abẹokuta, 2006 lo di Olowu ti ilu Owu.

To ba ṣe pe ojojo lo ṣi n ṣ’Ogun Kabiyesi, to ba si jẹ baba ti ṣipo pada naa ni, ALAROYE yoo maa fi to yin leti.

Leave a Reply