Olowu Kuta rọ awọn Musulumi: Ẹ jawọ ninu awọn iwa ti ko fogo f’Ọlọrun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Olowu Kuta, nipinlẹ Ọṣun, Ọba Hameed Oyelude Makama, ti rọ awọn Musulumi kaakiri agbaye lati ma ṣe gbagbe gbogbo ẹkọ ti aawẹ Ramadan ti wọn ṣẹṣẹ pari yii kọ wọn, ki wọn si yago gedegbe si awọn iwa ti ko fogo fun Ọlọrun.

Nini atẹjade kan ti kabiesi fi ṣọwọ si ALAROYElo ti pe fun ifẹ ati igbọra-ẹni-ye  laarin awọn Musulumi atawọn ẹlẹsin mi-in lorileede yii, ki alaafia pupọ le jọba, ki opin si de ba ede aiyede to n dina idagbasoke orileede Naijiria.

Ọba Makama ran awọn Musulumi leti pe asiko adura, ifara-ẹni-jin ati wiwa oju Ọlọrun lojoojumọ ti awọn Musulumi la kọja jẹ eyi to kọ wọn ni ifarada ati ijẹ-oloootọ si igbagbọ wọn.

O ni wọn gbọdọ lo awọn ẹkọ asiko naa lati jẹ ki alaafia jọba lagbegbe ti wọn n gbe, nitori eleyii ni orileede wa nilo lasiko ipenija nla ti a n koju lọwọlọwọ bayii.

Kabiesi rọ wọn lati jẹ aṣoju rere fun igbagbọ wọn nibikibi ti wọn ba wa, ki agbọye ẹsin wa laarin awọn ẹlẹsinjẹsin lorileede yii, ki alaafia si tubọ maa tẹsiwaju nipinlẹ Ọṣun.

O ni gbogbo awọn ti wọn lanfaani lati gba aawẹ naa ja ti ni isọdọtun ninu ẹmi lati jẹ ẹni alaafia, wọn yoo si ri ere rẹ gba, bẹẹ ni agbegbe wọn yoo janfaani ifara-ẹni-rubọ naa.

 

Leave a Reply