Oluṣọ ṣinu bi, o yinbọn mọ Kẹmi lẹsẹ l’Akute

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii lọwọ, ẹka ọlọpaa to n ṣewadii iwa ọdaran nipinlẹ Ogun ni Oluṣọ ṣọọṣi Sẹlẹ kan, Pasitọ Peter Oyedele, ti ijọ Jesu Yan Parish, Ọlambẹ Akute, nipinlẹ Ogun, wa. Wọn mu un sọdọ nitori ọmọ ọlọmọ to yinbọn mọ lẹsẹ, bẹẹ, iyẹn o ṣẹ ẹ lẹṣẹ kan, inu lo jọ pe o ṣi pasitọ bi.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, lo fi iṣẹlẹ yii lede lọsan-an ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji yii. Ninu ẹ lo ti ṣalaye pe ọkunrin kan torukọ ẹ n jẹ Deji Ọlaketan lo lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Ajuwọn, pe Oluṣọ tawọn ko mọ ri tẹlẹ naa yinbọn mọ ẹnikeji oun torukọ ẹ n jẹ Kẹmi Johnson lẹsẹ nigba tawọn wa aabo de ṣọọṣi rẹ.

Deji Ọlakẹtan ṣalaye fawọn ọlọpaa pe iṣẹ dẹrẹba loun n ṣe lọdọ ọga oun to jẹ obinrin, Kemi Johnson si n ṣe ọmọ ọdọ lọdọ obinrin kan naa.

O ni ọga awọn lawọn gbe lọ si papakọ ofurufu ti yoo ti wọ baalu lọ siluu oyinbo to n lọ, iya naa lo si paṣẹ pe kawọn gbe mọto pada sile mọlẹbi rẹ kan lẹyin tawọn ti gbe e de ẹẹpọọtu.

O tẹsiwaju pe mọto naa loun ati Kẹmi, ọmọ ọdun mejidinlogun, n gbe lọ sile mọlẹbi ọga awọn tawọn fi gbọ pe wọn n ṣe oro ni Ọlambẹ, awọn ko si le gba ibẹ kọja nitori ilẹ ti ṣu gidi.

O ni ẹnu aile kọja naa lawọn wa tawọn fi ri ṣọọṣi Sẹlẹ kan ti wọn ti n ṣe iṣọ oru lọwọ, lawọn ba kuku pinnu lati wọnu ṣọọṣi naa, kawọn si darapọ m’awọn to n ṣesin, iyẹn yoo le da aabo bo awọn kuro lọwọ awọn oloro.

Afi bi wọn ṣe wa lẹnu ọna ṣọọṣi, ti wọn ko ti i wọle, ti Oluṣọ ijọ naa si jade wa pẹlu ibọn gbọọrọ kan. Deji sọ pe Oluṣọ ko tiẹ ti i jẹ kawọn sọrọ kan bayii to fi da ibọn bo Kẹmi lẹsẹ.

Ohun to ṣẹlẹ ree ti dẹrẹba yii fi lọọ ṣalaye fun wọn ni teṣan ọlọpaa Ajuwọn, ti awọn ọlọpaa si fi lọọ gbe Oluṣọ Peter Oyedele. Ọta ibọn marun-un ti wọn ko ti i yin ni wọn tun ba lọwọ Oluṣọ, n ni wọn ba kuku gbe e sọkọ, o di teṣan, ibẹ lo si gba de ẹka itọpinpin.

Ẹsun meji ni wọn mu pasitọ yii fun, akọkọ ni igbiyanju lati paayan, ikeji si ni pe o ni nnkan ija lọwọ lai gbaṣẹ lati ni in.

Ni ti Kẹmi to yinbọn fun lẹsẹ, ọsibitu Jẹnẹra Ifakọ Ijaye ni wọn sare gbe e lọ, ibẹ ni wọn ti taari rẹ si LASUTH, n’Ikẹja, awọn iyẹn si ti ni ki wọn maa gbe e lọ sọsibitu elegungun, iyẹn Igbobi, l’Ekoo.

 

Leave a Reply