Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Akọwe ijọba apapọ orilẹ-ede yii nigba kan, Oloye Samuel Oluyẹmi Falae, ti gba ọpa aṣẹ gẹgẹ bii Ọba alade ti Ilu Abo, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọgbọnjọ, oṣu Kejila ọdun yii.
Oloye Falae to jẹ ọkan pataki ninu awọn ọmọ ẹgbẹ Afẹnifẹre wa lara awọn Olu ati ọlọja mẹrindinlaaadọrin ti wọn ṣẹṣẹ gba igbega sipo ọba alade lẹyin abọ iwadii igbimọ Onidaajọ Ajama, tijọba Arakunrin Rotimi Akeredolu gbe kalẹ lori ọrọ ọba ati oye jijẹ nipinlẹ Ondo.
Ninu ọrọ apilẹkọ rẹ lasiko ayẹyẹ ọhun, olori awọn oṣiṣẹ ọba nipinlẹ Ondo, Olugbenga Ale, to waa ṣoju gomina ni ijọba mọ riri ipa pataki tawọn ọba alaye n ko lori ifẹsẹmulẹ eto aabo lawọn agbegbe ti wọn jọba le lori.
O ni awọn ọba alaye naa wa lara awọn to yẹ ki ijọba fun lanfaani lati wa ojutuu ati ọna abayọ titi lae si ọrọ ipenija eto aabo to n mi orilẹ-ede Naijiria logbologbo lọwọ.
Akeredolu ni awọn eeyan ijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ soriire pupọ pẹlu bo ṣe jẹ pe ko din lawọn ọba mẹsan-an ti wọn jẹ anfaani gbigbega kuro nipo kan lọ si omiran nijọba ibilẹ ọhun nikan.
O ni Ọlọrun nikan ni i fi eniyan sipo adari, ati pe ko si ifun kan ninu oromọdiẹ eto iṣejọba Naijiria to ṣe ajoji si ọba tuntun naa latari awọn ipo nla nla to ti di mu sẹyin. O rọ Ọba Falae lati tẹsiwaju ninu akitiyan rẹ títì ti nnkan yoo fi bẹrẹ si i yipada si rere fun awọn eeyan orileede yii.
Gomina Akeredolu tun fi asiko ayẹyẹ naa kilọ fawọn ọba alaye nipinlẹ Ondo lati jawọ ninu awọn igbesẹ to le da omi alaafia ilu ru, o ni ijọba oun ko ni i laju silẹ maa woran ki awọn ọba maa fi ẹnikẹni joye lawọn agbegbe ti ki i ṣe tiwọn.
Ninu ọrọ soki ti Ọba Falae ba awọn eeyan sọ, o ni oun ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn eeyan Ilu Abo, ki wọn le jọ ṣiṣẹ pọ fun idagbasoke agbegbe naa.
Lara awọn to peju peṣẹ sibi ayẹyẹ ọhun ni: minisita feto irinna tẹlẹ, Rotimi Amaechi, Oloye Reuben Faṣọranti, Adebayọ Adewọle to jẹ oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu SDP, Eyitayọ Jẹgẹdẹ ati Deji tilu Akurẹ, Ọba Aladetoyinbo Aladelusi.