Olu Ilaro ni ki Buhari ati Dapọ Abiọdun tete dide si ipaniyan nilẹ Yewa, aijẹ bẹẹ…

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 

Lorukọ gbogbo ọba ilẹ Yewa atawọn igbimọ rẹ, Olu Ilaro, Ọba Kẹhinde Olugbenle, ti kegbajare si Aarẹ Muhammadu Buhari ati Gomina Dapọ Abiọdun lati dide si iṣoro awọn Fulani darandaran to n pa awọn eeyan kiri ni Yewa, ti wọn tun n dana sunle wọn pẹlu.

Opin ọsẹ yii ni Olu Ilaro fi atẹjade to fi kegbajare naa sita, nibi ti ọrọ ọhun si ka kabiyesi laya de, wọn fi kun un pe bijọba apapọ ati tipinlẹ Ogun ko ba tete fopin si rogbodiyan yii, awọn eeyan Yewa yoo bẹrẹ si i daabo bo ara wọn funra wọn.

 

Ohun ti eyi tumọ si ni pe kaluku yoo maa ni nnkan ija lọwọ bii tawọn Fulani, kawọn naa le gbeja ara wọn nigba tawọn to n pa wọn ba tun de.

Atẹjade naa sọ pe ko too di pe eyi yoo bẹrẹ si i ṣẹlẹ ni ọba alaye agba nilẹ Yewa yii ṣe n pe ẹka ijọba mejeeji lati tete wa nnkan ṣe o, aijẹ bẹẹ, awọn eeyan Yewa naa yoo yiju pada si Fulani.

Bakan naa ni Kabiyesi rọ awọn eeyan ilẹ Yewa lati tẹle ilana tijọba ipinlẹ Ogun ti la kalẹ lori eto aabo, lati ṣẹgun iṣoro to n koju awọn agbegbe bii Ọja-Ọdan, Ebute-Igboro, Imẹkọ-Afọn, Iselu, Egua, Owode-Ketu, Igan Alade, Gbokoto, Ijoun ati bẹẹ bẹẹ lọ.

 

 

Leave a Reply