Ọlawale Ajao, Ibadan
Lẹyin ti eto gbogbo ti pari lati fi Iyalode ipinlẹ Ọyọ jẹ, Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Owolabi Akinloye Ọlakulẹhin (Ige Ọlakulẹhin Kin-in-ni), ti fagi le eto ọhun, o ni wọn ko gbọdọ jẹ iru oye bẹẹ laelae.
Ẹgbẹ kan ta a forukọ bo laṣiiri ni wọn gbe eto naa kalẹ, wọn fẹẹ ṣe ohun ti ẹnikan ko ṣe ri, wọn fẹẹ fi ọkan ninu awọn gbajumọ obinrin oniṣowo Ibadan joye Iyalode gbogbo ipinlẹ Ọyọ.
Ọjọbọ ọsẹ yii, iyẹn, Tọsidee ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2024 yii, leto ọhun iba waye ni gbọngan Mapo, nigboro ilu Ibadan. Gbogbo imurasilẹ lori eto ọhun ni wọn si ti ṣe, titi dori ikede ati ipolongo lori redio.
Ṣugbọn lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹẹẹdọgbọn (25), oṣu yii, nigba ti ayẹyẹ ọhun ku ọjọ mẹta pere, l’Ọba Ọlakulẹhin paṣẹ pe wọn ko gbọdọ ṣeto naa.
Aṣẹ Olubadan yii waye lẹyin ipade ti oun pẹlu igbimọ rẹ ṣe laafin rẹ to wa l’Oke Arẹmọ, niluu Ibadan.
Lara awọn igbimọ ti wọn ṣepade pẹlu Olubadan ṣaaju aṣẹ ọba nla naa ni Ọba Rashidi Adewọlu Ladọja, ti i ṣe Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan; Ọba Tajudeen Abimbọla Ajibọla (Balogun); Ọba Kọlawọle Adegbọla (Ọtun Balogun), Ọba Eddy Oyewọle-Fọkọ (Osi Olubadan), ati Ọba Olubunmi Dada-Isioye ti i ṣe Osi Balogun ilẹ Ibadan.
Awọn yooku ni Aṣipa Olubadan Ọba Abiọdun Kọla-Daisi; Ashipa Balogun ilẹ Ibadan, Ọba Dauda Abiọdun Azeez; Ẹkẹrin Olubadan, Ọba Hamidu Ajibade ati Ẹkẹrin Balogun ilẹ Ibadan, Agba-Oye Akeem Mobọlaji Adewọyin.
Ninu atẹjade ti Ọgbẹni Solomon Oluwagbemiga Ayọade ti i ṣe Akọweeroyin Ọba Ọlakulẹhin, fi ṣọwọ sawọn oniroyin lorukọ Olubadan ati igbimọ rẹ, ni wọn ti fi aidunnu wọn han si bi ọrọ a n fi ni joye ṣe waa di tọ́rọ́fọ́nkálé bayii, to jẹ pe awọn eeyan ko tiẹ mọ iyatọ laarin oye ilu ati oye idanilọla mọ.
“A tiẹ gbọ pe awọn ontaja kan ti ọja ti wọn n ta ko ka lara, ti ko ara wọn jọ lati fi ẹnikan joye Iyalode ipinlẹ Ọyọ, lọjọ Tọsidee, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kọkanla, ọdun yii, igbimọ Olubadan si pa wọn laṣẹ lati jawọ ninu ipinnu naa ni kiakia.
“Oye ilu loye Iyalode, bi wọn ṣe n jẹ ẹ ni ilu kọọkan yatọ sira wọn. O loju ẹni ti i jẹ ẹ, ọba ni i si i fiiyan jẹ ẹ, ki i ṣe oye idanilọla ti awọn kan kan le kora wọn jọ ki wọn ni awọn fẹẹ fi ẹnikan jẹ iyalode.
“Awọn eeyan yii ma tiẹ waa fẹẹ doju aṣa bolẹ o. Ẹ ẹ gbọ na, nibo ni wọn gbọ pe wọn ti n joye Iyalode ipinlẹ kan. Agba-Oye Theresa Laduntan Oyekanmi, to jẹ Iyalode ilẹ Ibadan, odidi ọdun mejilelogoji (42) lo fi ni suuru ki oye yii too kan an. Bo ba tiẹ waa lẹtọọ si ẹnikẹni lati joye Iyalode ipinlẹ Ọyọ, ṣe wọn waa fẹ ki Iyalode Oyekanmi maa wari fun ẹnikan ti wọn kan deede fi oye Iyalode ipinlẹ Ọyọ ta lọrẹ ni? Ó doódì.”
Wọn waa rọ awọn to n gbero lati da iru palapala bẹẹ laṣa lati jawọ lapọn ti ko yọ fun anfaani ara wọn.
Ṣaaju ipade igbimọ Olubadan ọhun l’Ọba Ọlakulẹhin ti fi awọn ọmọ bibi ilu Ibadan kan joye Mọgaji agboole wọn. O si rọ awọn oloye tuntun naa lati maa ṣe pẹlẹpẹlẹ pẹlu awọn eeyan ti wo joye le lori.