Olubadan fi gomina Kano joye Aarẹ Fiwajoye ilẹ Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba (Ọmọwe) Mohood Lekan Balogun, ti fi Gomina ipinlẹ Kano, Ọmọwe Abdullahi Umar Ganduje, joye Aarẹ Fiwajoye ilẹ Ibadan, bẹẹ lo fi iyawo ẹ, Ọjọgbọn Hafsat Ganduje, jẹ Yeye Aarẹ Fiwajoye ilu naa.
Lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 yii, leto ọhun waye ni Gbọngan Mapo to wa niluu Ibadan.
Oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu pẹlu ọba ilu Kano, Emir Aminu Ado Bayero, wa lara awọn alejo pataki to wa nibi eto naa pẹlu Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ẹni ti Kọmiṣanna fọrọ ijọba ibilẹ ati ọrọ oye jijẹ nipinlẹ naa, Bayọ Lawal, ṣoju fun.
Diẹ lara awọn eeyan pataki to tun wa nibẹ ni
Emir ilu Kano, Alhaji Rano, Alhaji Kabiru Muhammed, Sẹnetọ Tẹslim Fọlarin, Sẹnetọ Bala Jubril, olori ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Kano.
Nigba to n sọrọ lori idi to ṣe fi Ganduje to jẹ ẹya Fulani joye ilẹ Ibadan, Olubadan sọ pe “nitori ki ajọṣepọ to dan mọran le wa laarin ilu Kano ati Ibadan ni. Igbagbọ wa ni pe ti alaafia ba wa ni Kano, to wa n’Ibadan, alaafia yoo wa ni gbogbo Naijiria.
Ọba Balogun, ẹni to sọrọ nipasẹ Sẹnetọ Kọla Balogun, aṣofin to n ṣoju ẹkun idibo Aarin-Gbungbun ipinlẹ Ọyọ nileegbimọ aṣofin agba ilẹ yii, sọ pe “nigba ti a n jiroro lori “emi lo kan” to ti di aṣa ti gbogbo aye n da yii, itumọ ta a fun un ni pe ẹyin lẹ maa di aarẹ, ki i ṣe pe ẹyin lo kan nikan, Naijiria lo kan, Afrika lo kan, lati ni idagbasoke lasiko iṣejọba yin.”
Ninu ọrọ tiẹ, Aṣiwaju Tinubu sọ pe ko wọpọ nilẹ Yoruba lati maa fi ẹni ti ki i ṣe ọmọ ilu joye. O ni, “Pẹlu eyi, o (Donina Ganduje) ti di ọmọ gbogbo ilẹ Yoruba niyẹn.
“Yatọ si iyẹn, ibaṣepọ to wa laarin ẹya mejeeji nipa ba a ṣe n fẹ ọmọ ara wa naa jẹ okun to so wa pọ. Igbesẹ ti Olubadan gbe yii yoo ṣokunfa alaafia ati ibagbepo rere laarin wa gẹgẹ bii nnkan pataki ti Alhaji Ganduje mu lọkun-un-kun-dun nitori bo ṣe fi ọmọbinrin rẹ fun wa (ọmọ Oloogbe Abiọla Ajimọbi) lati fi ṣaya.
Nigba to n dupẹ lọwọ Olubadan fun oye naa, Gomina Ganduje sọ pe “mi o lowo pupọ lọwọ lati fi ẹmi imoore han, ṣugbọn nnkan ti mo fẹẹ sọ ni pe Tinubu lo maa di aarẹ orileede yii. Eto to maa mu iṣọkan ba orileede yii wa ninu ipinnu rẹ.
‘‘Ko ya mi lẹnu pe ibaṣepọ ti gunmọ wa laarin Ibadan ati Kano, nitori ilu mejeeji lo tobi ju ni Naijiria. O mu mi ranti ibaṣepọ to wa laarin baba wa, Ado Bayero, atawọn agba oṣelu Ibadan ti wọn ti doloogbe.
“Mo ki Aṣaaju mi, ẹni ti mo fi ṣe awokọṣe, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu. Asiko ti iṣọkan ta a nilo lorileede yii maa tẹ wa lọwọ lo de tan yii. Emi naa fẹẹ darapọ mọ awọn ti n ṣadura fun ẹ pe iwọ lo kan”.

Leave a Reply