Olubadan rọ Yorùbá ati Hausa lati sinmi ìjà kia

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

 

Olubadan tilẹ Ibadan, Ọba Saliu Adetunji, ti rọ àwọn Yorùbá àti Fulani nilẹ Ibadan, paapaa lagbegbe Ṣáṣá, nigboro ilu naa, lati ki idà wọn bọ àkọ̀.

Ọba Adetunji parọwa yii leyin ipade to ṣe pẹlu awọn adari Fulani atawọn agbalagba Yoruba Ṣáṣá lọjọ Àbámẹ́ta, Satide.

Ìròyìn tó wà lójú ọpọn nipa ipinlẹ Ọyọ bayii lọrọ ija to waye laarin awọn Yorùbá atawọn Hausa ni Ṣáṣá, ninu eyi ti wọn ti paayan mẹrin, ti wọn sì dana sun ọkẹ àìmọye ile, ṣọọbu atawọn ohun irinṣẹ l’ọjọ Ẹtì, Furaidee.

Nitori laasigbo yii kan naa ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, fi ti ọja nla to wa lagbegbe naa pa lai ni gbèdéke ọjọ tí ìjọba tun máa ṣí i

Ọna lati dẹkun àjààjàtán ija yii lojoojumọ lo mu ki Olubadan ṣepade pajawiri pẹlu awọn adari igun mejeeji lagbegbe naa, ki alaafia le jọba.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Nigba ti wọn fi iṣẹlẹ yii to mi leti, Gómìnà Makinde ni mo kọkọ pe ta a sì sọrọ lori ọna ta a máa gba fopin sí rogbodiyan tó là ọpọ ẹmi eeyan ati dukia lọ yii.

“Mo ti sọ fún gomina lati wa nnkan gbà-má-bìínú fawọn to fara gbá nínú iṣẹlẹ yii.

“Gbogbo ẹ̀yà to wa nilẹ̀ Ibadan pata la rọ lati gba alaafia ati irẹpọ laaye, nitori ilu yìí ni wọn bi ọpọlọpọ àjèjì wọnyi si, ilu yìí náà là ti jọ kawe ta a si jọ dagba sí. Kò wáá sí ànfààní kankan tá a lè rí nínú ka máa fi asiko yii dojú ìjà kọra wa”.

 

 

Leave a Reply