Olubadan ti sọrọ o: Abẹ akoso Baalẹ Ṣaṣa ni Seriki Ṣaṣa wa

Faith Adebọla

Olubadan tilu Ibadan, Alayeluwa Ọba Saliu Adetunji, ti ṣalaye ipo akoso ilu Ṣaṣa, niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, kabiesi ni abẹ akoso Baalẹ ilu Ṣaṣa ni Seriki Ṣaṣa to jẹ alakooso awọn Hausa-Fulani ilu naa gbọdọ wa, ko si gbọdọ kọja ilana ati aṣa ilẹ Yoruba.

Nibi ipade alaafia kan ti wọn pe lati pẹtu saawọ to waye laarin awọn Yoruba ati Hausa to waye laipẹ yii ni ilu naa, eyi to mu rogbodiyan wa, ni ọba alaye naa ti sọrọ ọhun.

Ọtun ilẹ Ibadan, Agba oye Lekan Balogun lo fi iṣẹ Olubadan jẹ nibi ipade naa, o ni ilana to ti wa tipẹ nilẹ Yoruba, ati niluu Ibadan, ni pe Baalẹ lo n ṣakoso awọn agbegbe ilu ati ileto, ẹnikẹni to ba si jẹ ọba ẹya tabi ti awujọ kan niru agbegbe ati ileto bẹẹ, abẹ akoso baalẹ lo gbọdọ wa, tori baalẹ naa wa labẹ akoso ọba alaye ni.

O ni oye Sarkin Ṣaṣa ti wọn fi Alaaji Haruna Mai Yasin Katsina jẹ wulẹ jẹ oye apọnle lasan ni, ko si le paṣẹ ta ko ohun ti Baalẹ ilu Ṣaṣa, Oloye Amusa Ajani, ba sọ.

O ni bawọn kan ṣe n gbe ipo Sarkin Ṣaṣa gẹgẹ bii ẹni pe ọba alaye ni ko bojumu rara, o si ta ko ilana oye ati ọba jijẹ niluu Ibadan.

Kabiesi ni ki alaafia le wa, afi ki onikaluku mọ iwọn ara rẹ, abẹ akoso baalẹ ni ọba awọn Hausa-Fulani ti gbọdọ maa ṣakoso, akoso rẹ ko si gbọdọ kọja aarin awọn ẹya ati awujọ to jọba le lori.

Ọrọ ti Kabiesi sọ yii tubọ tan imọlẹ si awuyewuye to n lọ lori ẹrọ ayelujara, pẹlu bawọn kan ṣe n kọminu si aaye ati ipo ti Seriki awọn Hausa-Fulani naa wa niluu Ṣaṣa, wọn ni bi ọba naa ṣe kọ aafin rẹ, to si n jaye ọlọba laarin awọn Yoruba bii pe ọba Yoruba ni ko ba ilana ati aṣa oye jijẹ nilẹ Yoruba mu.

Leave a Reply