Olubadan yoo gbalejo Ọṣinbajo, Tinubu atawọn ọmọ Yoruba mi-in

Ọlawale Ajao, Ibadan

Igbakeji Aarẹ orile-ede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ni yoo ṣe idanilẹkọọ, nigba ti oludije du ipo aarẹ ilẹ yii lorukọ ẹgbẹ oṣelu All Progresives Congress (APC), Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ẹni to ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Eko, yoo jẹ alejo pataki laarin ọgọọrọ awọn eeyan pataki pataki nilẹ Yoruba nibi ayẹyẹ ọgọrun-un (100) ọjọ ti Ọba (Ọmọwe) Lekan Balogun gori itẹ gẹgẹ bii Olubadan ilẹ Ibadan tuntun.

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ni yoo gba gbogbo wọn lalejo nibi ariya alarinrin naa.

Ariya ti wọn fẹẹ ṣe fun Olubadan yii ni yoo waye lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlogun (19), oṣu Kẹfa, ọdun 2022 taa wa yii, ninu gbọngan ile nla kan ti wọn n pe ni John Paul II Building, to wa niwaju UI Bookshop, ninu ọgba Fasiti Ibadan.

Gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan ri, Sẹnetọ Rashidi Adewọlu Ladọja, to tun jẹ Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan, ni wọn fi ṣe alaga ayẹyẹ nla naa.

Nigba to n sọrọ nipa eto yii, Alakooso agba fun Ajọ Yoruba Agbaye, Ọgbẹni Alao Adedayọ, to tun jẹ oludasilẹ iweeroyin ALAROYE, ṣalaye pe “a fẹẹ fi oko kan pa ẹyẹ meji ni. Ohun ta a kọkọ gba lero tẹlẹ ni lati ṣajọyọ fun Olubadan tuntun laarin awọn ọba alade atawọn adari wa nilẹ Yoruba. Eyi lo si mu wa pe Igbakeji Aarẹ Ọṣinbajo ati Aṣiwaju Tinubu.

“Ṣugbọn a waa pada wo o pe awọn eeyan wa mejeeji ti wọn jẹ adari ijọba ati aṣaaju oloṣelu wọnyi ṣẹṣẹ de lati oju agbo idije oṣelu, eyi to ti da ọpọlọpọ awuyewuye silẹ laarin awa ọmọ Yoruba ti a n tẹle ẹni kin-in-ni tabi ẹni keji wọn ni, a waa fẹẹ lo oore-ọfẹ eto yii lati le da ajọṣepọ rere to ti wa laarin wọn tẹlẹ pada.

“A fi da gbogbo ọmọ Yoruba loju pe awọn mejeeji ni wọn yoo peju pesẹ sibi ayẹyẹ yii. Awa paapaa ko le sọ bi inu wa ṣe dun to nigba ta a ri idaniloju pe awọn mejeeji n bọ waa ba Olubadan ṣajọyọ.

“A o tori oṣelu pe wọn, nitori naa, ko saaye ọrọ oṣelu nibẹ, ohun ta a fẹ ni ki gbogbo awọn mejeeji pẹlu ẹni gbogbo to ba wa nibi ayẹyẹ yii ṣe ni lati wo awọn iṣẹ ọna Yoruba ta a fẹẹ ṣafihan lọjọ naa, ki wọn si wo ọna ti a le gba
jawe sobi aṣa ati iṣe Yoruba, ati ba a ṣe le lo o fun iṣọkan laarin wa, fun irolagbara awọn ọdọ wa, ati fun idagbasoke orileede yii lapapọ

Lọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun 2022, nijọba ipinlẹ Ọyọ, labẹ akoso Gomina Ṣeyi Makinde, de Ọba Lekan Balogun lade gẹgẹ bii Olubadan tuntun.
Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ta a fi eto yii si lo ṣe deede ọgọrun-un ọjọ ti Olubadan tuntun gori itẹ.

Ajọ Yoruba World Centre lo tẹ pẹpẹ ariya nla yii pẹlu atilẹyin ileeṣẹ eto iroyin, aṣa ati irinajo afẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ, ati Tunde Ọdunlade Gallery, iyẹn ileeṣẹ aṣa ati iṣẹ ọna to jẹ ti Ọmọọba Tunde Ọdunlade.

Leave a Reply