Oludamọran Fayẹmi lori eto oṣelu kọwe fipo silẹ, o darapọ mo ẹgbẹ SDP

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Oludamọran agba lori ọrọ to jẹ mọ eto idibo fun Gomina Kayọde Fayẹmi ti ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Olaiya Kupọlati, ti kọwe fipo rẹ silẹ, bẹẹ lo si tun kede pe oun n lọ sinu ẹgbẹ Ẹlẹṣin (SDP).

Ninu lẹta kan ti Ọgbẹni Kupọlati kọ ni ọjọ kẹtalelogun, ọṣu Kẹta, ọdun 2022, to fi ranṣẹ si ọfiisi akọwe ijọba ipinlẹ Ekiti, lo ti sọ pe ikọwe fipo silẹ oun yoo bẹrẹ ni ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹta, ọdun 2022 yii.

Kupọlati ṣalaye ninu lẹta naa pe kikọwe fipo silẹ oun waye pẹlu ibamu lori ofin eto idibo ti awọn aṣofin ijọba apapọ ṣẹṣẹ fọwọ si, to sọ pe oloṣelu to ba fẹẹ dije fun ipo gbọdọ kọwe fipo to wa silẹ ko too to oṣu mẹta ti yoo dije.

O ṣalaye pe oun ti gbero lati dije fun ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ekiti, ninu eto idibo gbogbogboo to n bọ ninu ẹgbẹ SDP.

Gẹgẹ bi lẹta naa ṣe sọ, “Emi Ọlaiya Kupọlati, to jẹ oludamọran agba fun Gomina Kayọde Fayẹmi lori eto idibo kede pe mo fi ipo mi silẹ lati ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹta, ọdun 2022.

“Mo fi asiko yii dupẹ lọwọ Dokita Kayọde Fayẹmi fun anfaani to fun mi lati sin ipinlẹ mi ati awọn eeyan mi.”

Nigba to n ṣalaye idi to fi darapọ mọ ẹgbẹ SPD ni wọọdu ẹkun idibo rẹ ni Iye-Ekiti, nijọba ibilẹ Ilejemeje, Kupọlati ṣalaye pe oun ri i pe oludije ninu ẹgbẹ Ẹlẹṣin, Oloye Sẹgun Oni, ni yoo jawe olubori ninu eto idibo gomina to n bọ nipinlẹ naa, ati pe oun lo ni imọ ju lọ lati dari ipinlẹ Ekiti ninu awọn oludije yooku.

Leave a Reply