Oludasilẹ ijọ ji awọn ọmọ ijọ rẹ meji gbe, o pa ọkan ninu wọn l’Ogun

Gbenga Amos, Abẹokuta

Awọn oludasilẹ ijọ kan ti wọn n pe ni Christian Fellowship Group, Life Builders Network, meji kan, Chidi Samuel ati Paul Zakari,  yoo rojọ ẹnu wọn yoo fẹẹ bo lakata awọn agbofinro pẹlu bi wọn ṣe ji meji ninu awọn ọmọ ijọ wọn gbe, ti wọn si pa ọkan ninu wọn ni Abule Ọya, to wa ni Imala, niluu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun. Awọn eeyan naa ni wọn pa Favour Okumazor to jẹ ọkan ninu awọn ọmọ ijọ wọn.

Nigba to n ṣafihan awọn ọdaran naa ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleweran, l’Abẹokuta, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle, ṣalaye pe awọn ọdọ kan ti wọn to bii meje ni awọn ọkunrin ti wọn pe ara wọn ni oludasilẹ ijọ naa ko lakata awọn obi wọn lọ si Abule kan ti wọn n pe ni Ọya, ti wọn ni awọn fẹẹ maa kọ wọn ni ọrọ Ọlọrun.

Ọkan ninu awọn ọdọ yii lo yọ kuro ni abule ọhun, to si lọọ sọ fun awọn obi wọn pe wọn ti pa ọkan ninu awọn. Obi awọn ọmọ yii lo lọọ fọrọ naa to ọlọpaa leti ti wọn fi mu awọn afurasi mejeeji.

Kọmiṣanna ọlọpaa ti ni ki wọn maa ko awọn eeyan naa lọ si ẹka to n ri si iwa ọdaran, nibi ti awọn eeyan naa yoo gba lọ si ile-ẹjọ nigba ti wọn ba pari iwadii lori ọrọ wọn.

Leave a Reply