Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ninu ibo ọọdunrun ti wọn di ni wọọdu oludije funpo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Biọdun Oyebamiji, mẹrin pere lo ṣẹku fun awọn alatako, mẹrindinlọọọdunrun loun nikan ko.
Wọọdu kẹfa, Yuniiti kẹta, Okelele, to wa Ikogosi-Ekiti, ni Oyebamiji ti dibo rẹ, to si ni ibo ọọdunrun din mẹrin, nigba ti ẹgbẹ PDP to wa ni ipo keji nibẹ ni ibo ẹyọ kan pere. Mẹta to ku ni wọn ko ka nitori ko kun oju oṣuwọn.
Check Also
Makinde yọ Jumọkẹ Akinjide kuro lara awọn oludibo abẹle ẹgbẹ PDP
Ọlawale Ajao, Ibadan Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde ti yọ orukọ Oloye Jumọkẹ Akinjide …