Oludije funpo aarẹ, Peter Obi, kọwe fipo silẹ ninu ẹgbẹ PDP

Jọkẹ Amọri
Oludije funpo aarẹ lorukọ ẹgbẹ PDP, to tun figba kan jẹ gomina ipinlẹ Anambra, Peter Obi, ti fi ẹgbẹ naa silẹ, bẹẹ lo si ti kọwe pe oun ko ṣe oludije lorukọ ẹgbẹ naa mọ.
Ninu lẹta kan ti Oludari ipolongo rẹ, Dokita Doyin Okupe, fi silẹ ni ileeṣẹ ẹgbẹ naa l’Abuja l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lorukọ ọkunrin naa lo ti sọ eyi di mimọ.
Ninu iwe ti ọkunrin naa kọ si Alaga ẹgbẹ wọn, Iyorchia Ayu, lo ti sọ pe awọn ohun to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa lẹnu ọjọ mẹta yii jẹ idi pataki fun oun lati fi ẹgbẹ naa silẹ, ki oun si tun jawọ ninu didije fun ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ ọhun.
Obi wa ninu awọn oludije meeedogun to fẹẹ dupo aarẹ lorukọ ẹgbẹ PDP. Ko ti i sẹni to mọ boya ọkunrin naa ni i lọkan lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu mi-in.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//thaudray.com/4/4998019
%d bloggers like this: