Olujimi ṣedaro Ọlasunkami, jagunjagun to ku sinu ijamba ọkọ ofurufu

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

 

Sẹnetọ Biọdun Olujimi to n ṣoju awọn eeyan Guusu Ekiti ti

ṣedaro Flight Sergeant ̣Ọlasunkanmi Ọlawumi, ṣọja ofurufu to ku sinu ijamba

baaluu lọjọ Aiku, Sannde, niluu Abuja.

Olasunkanmi atawọn ọmọ-ogun mẹfa mi-in ni wọn lugbadi ijamba ọhun lasiko ti wọn fẹẹ gbera lati Abuja lọ si Minna, olu-ilu ipinlẹ Niger.

Olujimi ṣapejuwe iku ọmọ Ọgọtun-Ekiti, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ekiti, ọhun gẹgẹ bii eyi to ba ni lọkan jẹ jọjọ, bẹẹ lo ni ajalu nla lo jẹ fun baba ẹ to ti darugbo.

O ni ọmọluabi ni Ọlasunkanmi nigba aye ẹ, bẹẹ lo jẹ apẹẹrẹ rere laarin

awọn ẹgbẹ ẹ, eyi to jẹ ki iku ẹ ba ọpọlọpọ nnkan jẹ.

”Ọlasunkanmi ni baba to bi i ti dagba daadaa, to si n wo o gẹgẹ bii ẹni ti yoo ṣele de e, eeyan pataki si ni baba naa lawujọ.

”Ọmọ gidi ni oloogbe nigba aye ẹ, mo si gbadura pe ki Ọlọrun tu mọlẹbi ẹ ati tawọn mẹfa to ku ninu.”

Olujimi waa rọ awọn alaṣẹ lati ṣewadii ijinlẹ lori iṣẹlẹ naa, ki wọn si gbe igbesẹ to yẹ.

 

 

Leave a Reply