Florence Babaṣọla
Olukọ Fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ, Ileefẹ, ti awọn ọmọ igbimọ oluṣakoso ileewe naa da duro laipẹ yii lori ẹsun pe o tasẹ agẹrẹ si akẹkọọ-binrin kan, Dokita Adebayọ Mosọbalaje, ti sọ pe mọkaruuru ni igbesẹ ti igbimọ naa gbe.
O ni oun yoo gbe ọrọ naa lọ sile-ẹjọ lati pe igbesẹ awọn igbimọ ọhun nija, nitori o ta ko ẹtọ ọmọniyan pẹlu ofin to n ṣakoso ibaṣepọ laarin olukọ ati akẹkọọ ni fasiti naa.
Nigba to n sọrọ lori bi wọn ṣe yọ ọ niṣẹ, Mosọbalaje ṣalaye pe igbimọ to maa n fiya jẹ ẹnikẹni to ba huwa aitọ ni fasiti naa, Council Disciplinary Panel ati Joint Senate, ti wọn wadii ẹsun naa sọ pe ko si ẹri arigbamu kankan pe ohun huwa naa, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ bi awọn igbimọ oluṣakoso ṣe kede idaduro oun.
O ni ọdun 2013 ni akẹkọọ-binrin naa wọle si OAU, ọdun 2017 lo si wa si ọfiisi oun lati beere nipa projẹẹti aṣekagbaa ẹkọ rẹ, ọjọ naa si ni wọn ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.
O sọ siwaju pe lọjọ karun-un, oṣu keje, ọdun 2018, ni ẹnikan lati Center for Gender ba akẹkọọ-binrin naa kọwe ẹsun mọ oun lẹsẹ lọ siwaju Giiwa fasiti naa, Eyitọpẹ Ogunbọdẹde.
Mosọbalaje sọ pe giwa gbe igbimọ oluwadii kan kalẹ, oun si kọwe fipo silẹ gẹgẹ bii ọmọ igbimọ oluṣakoso fasiti naa (university’s governing council), oun si sọ fun igbimọ naa pe irọ to jinna soootọ ni ẹsun naa.
O ni akẹkọọ-binrin naa sọ pe oun ka (recorded) iṣẹlẹ naa silẹ lọdun 2017, iwadii si bẹrẹ lọdun 2018, obinrin naa si tun sọ pe iṣẹlẹ naa ko ni ipa kankan lori maaki ti oun gba jade.
Ọkunrin yii ni ọdun 2006 loun darapọ mọ fasiti naa bii olukọ, ko si si ẹsun kankan to jọ mọ eleyii nipa oun ri, bẹẹ ni oun ko gba iwe ‘waa wi tẹnu ẹ’ ri rara.
O fi kun ọrọ rẹ pe olufisun oun ko figba kankan yọju siwaju igbimọ oluwadii, bẹẹ ni ko sẹni to mọ ohun (voice) awọn ti wọn n sọrọ ninu fọnran (tape) ti wọn fi ka ẹsun si oun lẹsẹ.