Stephen Ajagbe, Ilorin
Olukọ ileewe giga College of Health Technology, niluu Ọffa, nipinlẹ Kwara, Ọpaṣhọla Abdullahi, ti ha sọwọ ajọ to n gbogun tiwa ibajẹ ati jibiti, EFCC, fẹsun ṣiṣe jibiti lori ẹrọ ayelujara.
Ọpaṣhọla, ni EFCC wọ lọ sile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara nitori bi wọn ṣe ni o n lo foto ati orukọ obinrin lati maa fi lu awọn ọkunrin oyinbo ni jibiti.
Afurasi naa wa lara awọn ọmọ ‘Yahoo’ mejilelọgbọn tọwọ EFCC tẹ niluu Ọffa lọjọ kẹrinla, oṣu kẹsan-an, ọdun 2020.
Olukọ ọhun to n lo ayederu orukọ, ‘Devin Snow’ ni wọn fẹsun kan pe ninu oṣu kẹjọ, ọdun 2020, o lo ikanni ‘gmail’ kan; devinesnow677@gmail.com, lati fi tan ọkunrin oyinbo kan, Eugene Myvett, pe oun nifẹẹ rẹ, to si ni kiyẹn fi dọla ọgọrun-un meji ranṣẹ soun.
Nigba tile-ẹjọ ka ẹsun naa si i leti, ọkunrin naa loun jẹbi loootọ. O ni ki adajọ foju aanu wo oun.
Agbẹjọro ijọba, Ọgbẹni Andrew Akoja, ke si ọkan lara awọn oṣiṣẹ EFCC, Paul Kera, lati fun ile-ẹjọ ni ẹkunrẹrẹ bi ẹjọ naa ṣe jẹ ati bi ọwọ ṣe tẹ afurasi naa.
Kera ṣalaye pe awọn gba iwe-ẹsun lori itu tawọn onijibiti ori intanẹẹti n pa niluu Ọffa, lasiko iwadii awọn lọwọ tẹ Ọpaṣhọla.
O ni nigba tawọn tu ile rẹ wo yẹbẹyẹbẹ, awọn ba foonu ‘Infinix’ kan to maa n lo lati fi lu jibiti lori ẹrọ ayelujara nibẹ. Gbogbo ẹri akọsilẹ ohun ti wọn gba lẹnu rẹ ati foonu to n lo naa lajọ EFCC ko siwaju ile-ẹjọ.
Akoja ni niwọngba ti olujẹjọ naa ti gba pe oun jẹbi, ki adajọ ṣe ẹjọ rẹ kiakia.
Adajọ Adenikẹ Akinpẹlu sun idajọ rẹ si ọjọ kẹtalelogun, oṣu keji, ọdun yii. O ni ki afurasi naa ṣi wa lahaamọ EFCC titi di ọjọ naa.