Olukọ ileewe giga fi foto obinrin lu oyinbo ni jibiti niluu Ọffa

Stephen Ajagbe, Ilorin

Olukọ ileewe giga College of Health Technology, niluu Ọffa, nipinlẹ Kwara, Ọpaṣhọla Abdullahi, ti ha sọwọ ajọ to n gbogun tiwa ibajẹ ati jibiti, EFCC, fẹsun ṣiṣe jibiti lori ẹrọ ayelujara.

Ọpaṣhọla, ni EFCC wọ lọ sile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara nitori bi wọn ṣe ni o n lo foto ati orukọ obinrin lati maa fi lu awọn ọkunrin oyinbo ni jibiti.

Afurasi naa wa lara awọn ọmọ ‘Yahoo’ mejilelọgbọn tọwọ EFCC tẹ niluu Ọffa lọjọ kẹrinla, oṣu kẹsan-an, ọdun 2020.

Olukọ ọhun to n lo ayederu orukọ, ‘Devin Snow’ ni wọn fẹsun kan pe ninu oṣu kẹjọ, ọdun 2020, o lo ikanni ‘gmail’ kan; devinesnow677@gmail.com, lati fi tan ọkunrin oyinbo kan, Eugene Myvett, pe oun nifẹẹ rẹ, to si ni kiyẹn fi dọla ọgọrun-un meji ranṣẹ soun.

Nigba tile-ẹjọ ka ẹsun naa si i leti, ọkunrin naa loun jẹbi loootọ. O ni ki adajọ foju aanu wo oun.

Agbẹjọro ijọba, Ọgbẹni Andrew Akoja, ke si ọkan lara awọn oṣiṣẹ EFCC, Paul Kera, lati fun ile-ẹjọ ni ẹkunrẹrẹ bi ẹjọ naa ṣe jẹ ati bi ọwọ ṣe tẹ afurasi naa.

Kera ṣalaye pe awọn gba iwe-ẹsun lori itu tawọn onijibiti ori intanẹẹti n pa niluu Ọffa, lasiko iwadii awọn lọwọ tẹ Ọpaṣhọla.

O ni nigba tawọn tu ile rẹ wo yẹbẹyẹbẹ, awọn ba foonu ‘Infinix’ kan to maa n lo lati fi lu jibiti lori ẹrọ ayelujara nibẹ. Gbogbo ẹri akọsilẹ ohun ti wọn gba lẹnu rẹ ati foonu to n lo naa lajọ EFCC ko siwaju ile-ẹjọ.

Akoja ni niwọngba ti olujẹjọ naa ti gba pe oun jẹbi, ki adajọ ṣe ẹjọ rẹ kiakia.

Adajọ Adenikẹ Akinpẹlu sun idajọ rẹ si ọjọ kẹtalelogun, oṣu keji, ọdun yii. O ni ki afurasi naa ṣi wa lahaamọ EFCC titi di ọjọ naa.

Leave a Reply