Olukọ to ba tun ran akẹkọọ niṣẹ ti ko tọna l’Ondo yoo ri pipọn oju ijọba

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ijọba ipinlẹ Ondo ti kede ipinnu rẹ la ti maa fiya jẹ olukọ tọwọ ba tẹ pe o n lo akẹkọọ rẹ ni nilokulo lasiko ti wọn ba wa nileewe.

Oludamọran fun gomina lori akanṣe iṣẹ, Dokita Doyin Ọdẹbọwale, to sọrọ yii lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii. O  ni ọpọlọpọ awọn olukọ ipinlẹ naa ni ẹsun wọn ti wa niwaju ijọba lori awọn iṣẹ ti ko tọ ti wọn n fun awọn akẹkọọ wọn ṣe nileewe.

O ni oriṣiiriṣii iroyin lawọn n gbọ lori bawọn tiṣa kan ṣe n ko awọn akẹkọọ lọ sile tabi oko wọn la ti ba wọn ṣiṣẹ, leyii to lodi sofin ati ilana to rọ mọ eto ẹkọ ipinlẹ Ondo.

O rọ awọn olukọ ti wọn n hu iru iwa yii ki wọn tete jawọ, nitori pe ijọba ti ṣetan ati fiya to tọ jẹ ẹni to ba tun dan iru rẹ wo.

Nigba to n fun oludamọran ọhun lesi, Alaga ẹgbẹ awọn olukọ ileewe alakọọbẹrẹ, Ọgbẹni Victor Akọmọ, ni ko sibi ti wọn ti n fawọn akẹkọọ ṣiṣẹ ile mọ lasiko ta a wa yii.

 

O ni kijọba lọọ fọkan balẹ, nitori pe ahesọ lasan ni iroyin ọhun jẹ.

Leave a Reply