Olukọ to fara gbọta lasiko tawọn agbebọn fẹ ji tiṣa meji gbe ni Kwara ṣi n gbatọju lọsibitu

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, ni tiṣa kan ti wọn o darukọ fara gbọta lasiko ti awọn agbebọn fẹẹ ji awọn tiṣa obinrin meji kan to jẹ ti ileewe girama niluu Osi, nijọba ibilẹ Ekiti, nipinlẹ Kwara, gbe lọ.

Agbẹnusọ ajọ ẹsọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Babawale Zaid Afolabi, lo fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ pe awọn olukọ meji ni wọn dari bọ lati ileewe ti wọn ti n kọ awọn ọmọ ni nnkan bii aago mẹrin aabọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, ti awọn agbebọn to dihamọra pẹlu ibọn ati ohun ija oloro miiran si da wọn lọna, ti wọn fẹ ji wọn gbe, ṣugbọn ori ko wọn yọ, bo tilẹ jẹ pe olukọ kan fara kaasa ọta ibọn, to si ti n gba itọju bayii nileewosan kan ti wọn o darukọ niluu ọhun.

Afọlabi tẹsiwaju pe ṣe ni awọn gba ipe lojiji ni ọfiisi ajọ naa to wa ni Ararọmi Opin Ekiti, nipinlẹ Kwara, ti ajọ NSCDC pẹlu ajọṣepọ fijilante ati awọn ẹsọ alaabo miiran si ya bo agbegbe naa, ko too di pe awọn agbebọn naa sa wọgbo lọ. O fi kun un pe gbogbo awọn ẹsọ alaabo pata lo ti kan lugbo bayii lati ri i pe ọwọ tẹ awọn afurasi ọdaran agbeni pawo naa.

Leave a Reply